Gbogbo eto lo ti pari lori ayeye odun kan lori
apere, eyi ti Aare Onakakanfo ile Yoruba, Iba Gani Abiodun Ige Adams fe se
laipe yii.
Ninu atejade ti oluranlowo fun un lori eto
iroyin, Ogbeni Kehinde Aderemi, niyen ti fidi e mule wi pe ojo merin gbako ni eto ohun
yoo fi waye, eyi ti yoo bere lojo kewaa osu kin-in-ni odun to n bo titi dojo
ketala osu ohun, ninu eyi ti eto lolokan-o-jokan yoo ti waye pelu.
Lara ohun pataki ti won yoo gbe se lasiko naa
ni idanilekoo ita gbangba, ifilole iwe apileko, ifami-eye-da awon omo orile-ede
yii ti won laami-laaka lola, isafihan ise ona lorisirisi ati ayeye ti won yoo
fi kadii eto ohun nile.
Ninu oro Aare Onakakanfo, Iba Gani Adams lo ti
so pe, "Latigba ti mo ti gori oye yii ninu osu kin-in-ni odun to koja ni
mo ti n sa ipa mi lati ri i pe a lo ipo ohun fun ilosiwaju eya Yoruba. Ti a ba
n so nipa ipo Aare Onakakanfo nile Yoruba, ipo nla kan ni to ti wa lati odun 1630,
eni to si koko je oye ohun ni Alaafin Ajagbo. Oye isenbaye ni to ti wa lati bi egbeta-odun-o-din-mejila
(588), bee la o le foju yepere woru oye bee.
“Bo tile je pe alaafo die si sile, ti ko seni
kan bayii to joye ohun fodun pipe, sibe oye lasan ko o, bee lo fi irufe ipo ti
oye ohun wa han nile Yoruba.”
O fi kun oro e wi pe, “Fun idi eyi, lodoodun
la o maa sayeye ayajo ojo ti mo gori oye yii, bee gege ni mo fe lo alakooko iru
e yii lati foye nla da awon omo Yoruba, lokunrin ati lobinrinm lola, paapaa
awon ti won wa lati apa iha Iwo-oorun orile-ede yii. Irufe awon eeyan ti a n so
yii lawon omoluabi ti won ti lo ipo won lati tan imole nla ti Olodumare fun
iran Yoruba kaakiri agbaye. Bakan naa ni a ti ni alakale eto bi ohun gbogbo yoo
se lo daadaa.”
Iba Gani Adams tun te siwaju pe, “Lori oro oye
ti a fe fi da awon eeyan lola, o ti ni awon eeyan pataki ti a fe fun loye, bee
lori ise takuntakun ti won ti se fun iran Yoruba la se fe fun won.”
Ni bayii, awon ojulowo eeyan merinla ti a fe
fun loye yii, kaakiri ile Yoruba ni won ti mu won leyin ise iwadii olowo iyebiye
tawon igbimo ohun ti se, bee awon eeyan ti won mu yii, ojulowo ni won, ninu ise
ati okoowo ti kaluku won gbe dani. Lara won naa ni, awon akosemose, awon
ojogbon onimimo; awon eeyan nla ti won mo tifun-tedo asa ati isese wa, awon
ojogbon nidii ise iroyin; gbajugbaja onisowo ati awon onimo ofin.” Iba Gani
Adams lo so o.
Bakan naa lo ti sapejuwe ofiisi Aare
Onakakanfo yii bi aaye nla kan ti ojulowo asa ati isese Yoruba ti fidi mule
daadaa, ati pe aye pataki kan ni ti igbelaruge e se pataki fun gbogbo eya
Yoruba patapata.
Ninu oro Dr. Abiola Ayankunbi, okan ninu awon
omo igbimo ohun lo ti so pe, ti a ba ni ka wo ipo nla ti Aare Onakakanfo, Iba
Gani Adams di mu nile Yoruba ati awujo wa lapapo, orisirisi eto lati la kale ki
ohun ti a fe se yii le kesejari. Eto ti a fe fi ojo merin se yii, a o lo si
mosalasi, soosi, bee lawon elesin abalaye naa ni ipa tiwon ti won maa ko.
Ojo ketala osu kin-in-ni odun to koja ni
Alaafin Oyo, Oba Adeyemi Atanda Lamidi fi Iba Gani Abidoun Adams joye nla yii
gege Aare Onakakanfo keedogun nile Yoruba, eyi to waye ni Durbar stadium niluu
Oyo.
0 Comments