O fe je pe
ni kete ti gomina ipinle Ekiti tele ti kuro nipo, ojoojumo bayii niroyin
orisirisi n gba igboro nipa gbajumpo oloselu yii.
Ohun to
tun wa nita bayii ni bi egbe oselu PDP se tu ile ka, iyen igbimo to n ri si oro
egbe oselu PDP nipinle naa, nibe gan-an ni won ti yo Fayose nipo, ti won si gbe
ipo asaaju egbe naa le Seneto Abiodun Olujinmi, eni to ti figba kan je igbakeji
gomina ninu ijoba Peter Ayodele Fayose ri l’Ekiti.
Ohun ta a
gbo pe o fa sabaabi isele yii ni bi won se n gba awon owo kan ninu apo ikowosi
egbe naa nipinle Ekiti, eyi gan an ni won lo mu won tu ile ka.
Niluu Ado-Ekiti
nibe gan-an ni igbese ohun ti waye, nibi ti igbimo to ga ju ninu egbe oselu
ohun ti gbese le apo ikowosi egbe naa, ti won si yan Seneto Abiodun Olujinmi
gege bi asaaju egbe naa nipinle Ekiti ati nile Yourba lapapo.
0 Comments