Titi di asiko yii ni
inu gbajumo olorin esin Islam nni, Alhaja Rodiyat Sanni Adeboye n dun sinkin,
ti obinrin naa n dupe lowo Olorun fun iru oko ti o yan fun un.
Ohun ta a gbo ni pe bo
se ku dede ki Alaaja Rodiyat Sanni Adeboye, okan lara awon olorin esin Islam to
n se daadaa niluu Dublin, lorile-ede Ireland lohun-un se ojoobi e ni Mathew Ididowo,
eni ti se oko gbajumo olorin musulumi yii ti gba studio lo, orin nla kan loun
ati awon produsa ko jo, nni won ba pe Alaaja Mariam Akiiki, ki o wa ko o sinu
fonran, bi won se se rekoodu fun ojoobi Rodiyat, eni tawon eeyan tun mo si
Hello Olorun niyen.
Bi manija Alhaji Wasiu
Alabi Pasuma atawon eeyan e se pari rekoodu ohun, ti won toju e, bee ni won ko
je ki enikeni mo, bo si ti ku iseju winni-winni ki ojoobi Rodiyat pe, nise ni
Ididowo gba ori ikanni ayelujara lo, facebook atawon mi-in, nibe gan-an ni Rodiyat
ti ri orin idunnu ti won se fun un yii lati fi sami eye nla ohun.
Ninu oro gbajumo
olorin Islam yii lo ti so pe, “Ohun idunnu nla ni AY se fun mi, o se bebe o, ki
i Olorun tubo ba mi ke e, ife to wa laarin wa ko ni i baje lase Olorun. Bakan
naa ni mo dupe lowo Alhaja Mariam Akiiki, ti won fi imo nla ti Olorun jogun fun
won gbe orin naa kale, ajosepo gbogbo wa pata ko ni i baje.”
Ni bayii, ariya nla lo
n lowo lowo niluu Dublin nibi ti Alhaja Rodiyat Sanni Adeboye n gbe, bee lawon
ololufee e kaakiri agbaye ti n ki i, ti won n ba a yayo ojoobi e yii.
Lara awon olorin to n
se bebe nidii orin Islam ni obinrin yii, eni to je akosemose nidii ise olutoju
(Nurse) ko too di olorin nla niluu Dublin.
Awon rekoodu wonyii;
Hello Olohun, Islamic News, I love Muhammad and Allahu loun naa ti se, ti won
si n se daadaa laarin awon orin Musulumi yooku to wa nigboro.
0 Comments