Tusde
ogunjo osu yii lawon Musulumi kaakiri agbaye yoo bere ayeye ayajo ojoobi Anobi
Muhammed.
Ni
bayii, ijoba apapo ti kede isinmi olojo kan fun ayeye naa, eyi to maa waye lojo
Isegun to n bo yii. Ninu oro Minisita fun oro abele, Ajagunfeyinti Abdulrahman Dambazau to se ikede ohun loruko
ijoba apapo orile-ede yii lo ti ni ki awon Musulumi lo akoko naa lati fi wa
ojuure Olorun, ki won si gbiyanju fi iwa daadaa jo Anobi.
O fi
kun un pe, iwa ododo, iwa mimo, ifaaye-gba omlakeji ati ibagbepo alaafia ti
Ojise nla ni lo fi gbayi julo lagbaye.
0 Comments