Nibi ipade ti egbe oselu PDP se
loni-in ni won ti ke si oga agba nileese olopaa ati alaga ajo INEC lati kowe
fipo won sile, bi eto idibo gbogbogboo se n sunmo etile.
Ohun ti awon omo egbe oselu PDP
so ni pe awon ko nigbagbo kankan ninu oga agba fun ajo eleto idibo orile-ede
yii, iyen Ojogbon Yakub nitori ko jo wi pee to idibo to le moyan lori le waye
lodun to n bo.
Won fi kun oro won pe eto idibo
to waye lawon ipinle bii Ekiti, Osun ati eyi ti won di ni Kwara laipe yii ti fi
han wi pe alaga ajo naa, Ojogbon Yakubu ko ni i le seto dibo ti ko ni i ni
makaruru ninu.
Bee gege ni won so pe, oga agba
ileese olopaa, Ibrahim Idris paapaa ko see fokan tan, nitori o see se ko lo
awon olopaa lati fi doju eto idibo ohun ru.
Ninu oro Aare ile igbimo asofin,
Seneto Bukola Saraki nibi ipade ohun lo ti so pe, bo tile je pe ko rorun lati
gba akoso lowo ijoba to ba wa lori ipo ninu eto idibo, sibe egbe oselu PDP
setan lati fibo le Aare Muhammed Buhari kuro nipo ijoba, nitori o ti sele ni
Nigeria ri, nibi ti egbe oloselu alatako ti jawe olubori.
Saraki ti so pe iru e gan-an ni
yoo sele si ijoba APC lodun to n bo, nibi tawon yoo ti dojuti Buhari ati egbe
oselu re.
Ninu oro Omooba Secondus, eni
ti se alaga egbe oselu PDP lo ti ke si alaga ajo eleto idibo ati oga olopaa
lati kowe fipo sile, nitori ko daju wi pe won le seto idibo ti ko ni i ni
ojooro ninu.
Ninu oro Alhaji Atiku Abubakar
ni tie lo ti ke si gbogbo omo egbe oselu ohun pata atawon oloselu ti won di ipo
orisirisi mu ninu egbe naa lati ji giiri, ki won le le egbe oselu APC kuro nipo
ijoba.
Bakan naa ni Atiku tun ke si
Aare Muhammed Buhari wi pe ko jade s’oju ogbagede, nibi tawon mejeeji yoo ti jo
sariyanjiyan lori ohun ti won fe gbe se fun orile-ede Nigeria.
Okunrin to ti se aare orile-ede
yii ri nigba kan ti fi da awon eeyan orile-ede yii loju wi pe, egbe oselu PDP
ni yoo gbakoso ijoba to ba di lodun 2019, ati pe igbe aye irorun ti egbe naa n
gbe e bo wa, igban otun lo maa je fun kaluku ni Nigeria.
0 Comments