GBAJUMO

NITORI IKU OPE BADEMOSI: WON TI FAGILE AYEYE EKIMOGUN L’ONDO


Oloogbe Bademosi, Lotin ilu Ondo
Awon igbimo to n ri si ayeye Ekimogun Day to maa n waye lodoodun niluu Ondo ti fagile ayeye ohun.
Ninu atejade kan ti Alhaji Yemi Adewetan, eni ti se alukoro fun igbimo eleto ayeye ohun fowo si lo ti so pe, igbimo naa gbe igbese ohun latari iku ojiji to pa alaga ayeye naa, iyen Oloye Ope Bademosi.
Siwaju si i, ninu atejade yen ni igbimo ohun, Ondo Development Committee ti so pe, “Leyin ipade ta a se pelu awon Oloye Osemawe-in-Counil lati gbase lati fagile ayeye Ekimogun todun yii. Igbese ohun waye lati fi sedaro alaga wa, Ope Bademosi to ku, eni ti se okan lara awon ogunna gbongbo omo ilu yii to pile ayeye Ekimogun day ta a maa n se lodoodun. A n fi asiko yii ro gbogbo omo ilu Ondo, ki won maa fi adura ran wa lowo, ki alaafia to peye le joba niluu abinibi wa.”
Ose to koja ni Oloye Ope Bademosi jade laye, okunrin kan ti won pe oruko e ni Sunday Anani to maa n dana ounje fun won nile e l’Ekoo ni won so pe o seku pa a.
Agbegbe kan ti won n pe ni Yabaa niluu Ondo lowo ti te okunrin afura si yii leyin ti won so pe o sise laabi ohun tan l’Ekoo.
Ni bayii, awon olopaa ti mu un, bee ni won ti n foro wa a lenu wo lori isele ohun. Bakan naa la gbo pe iyawo Oloogbe naa ti wa lowo awon olopaa nibi toun naa ti n ran won lowo lori isele buruku yii.
Nipinle Ondo, ayeye nla ni Ekimogun je, kaakiri agbaye ti awon omo Ondo wa ni won ti maa n wa sile lati wa kopa ninu ayeye ohun, eyi to maa n mu ilu Ondo dun yungba, sugbon o seni laanu wi pe ayeye ohun ko ni i see se lodun yii nitori iku ojiji to pa okan lara awon ojulowo omo ilu naa, to je agbateru e, iyen Oloye Ope Bademosi, eni ti se Oloye Lotin tilu Ondo.
Omo Togo ti won lo pa a
Te o ba gbagbe, adugbo kan ti won n pe ni Park View lane n’Ikoyi l’Ekoo nisele ohun ti waye lojo kokanlelogbon osu kewaa odun yii.Won ni ko ju ojo keta ti won gba okunrin omo Togo yii, Sunday Anani sise ni won lo seku pa alaga ileese Credit Switch Tehnology, Ope Bademosi.
Nigba towo te e, alaye to se ni pe oun ko mo nipa iku to pa okunrin naa.

Post a Comment

0 Comments