GBAJUMO

ONIBATA JESU FE GBALEJO IYAWO OONI TUNTUN, OLORI SILEKUNOLA OGUNWUSI L’EKOO


Sannde, ojo keji osu yii ni gbajumo olorin emi nni, Efanjeliisi Funke Ojo, eni tawon eeyan tun mo si Onibata Jesu yoo se ikojade orin e tuntun to pe akole e ni AT LAST O JA SOPE.
Nipinle Eko nile ijosin RCCG Flourish Land Assembly, to wa ni nomba 18 Michael Adekoya, legbee Sura Mogaji Street, n’Ilupeju, l’Ekoo lo so pe eto ohun yoo ti waye.
Lara awon eeyan pataki ti gbajumo olorin emi yii n reti lojo naa ni Yeyeluwa Silekunola Naomi Ogunwusi, eni ti se iyawo Ooni Ile-Ife.
Bakan naa ni Baba Isale egbe akorin e, Oloye Dr. Ebenezer Obey Fabiyi naa yoo wa nikale lojo naa.
Ninu oro Onibata Jesu lo ti so pe, “Mo fi gbogbo ope ati iyin fun Olorun to fun mi ni oore ofe lati se rekoodu tuntun yii, eyi ti yoo migboro titi. Ninu ohun gbogbo, ohun kan pataki ti Oluwa fe fun wa naa ni ki a maa dupe, nitori e ni mo se pe akole e ni AT LAST O JA SO PE.

“Igbagbo mi ni pe ohunkohun ti kaluku n la koja ni wakati owo yii, mo nigbagbo wi pe ope lo maa ja si nigbeyin oro. Orin iyin fun Olorun ni, bee lo tun je orin adura ati waasu ti o le gba emi eeyan la, ti okan eeyan yoo si maa fa si Olorun alaaye.”
Siwaju si i, akorin emi yii, eni ti se omo Ikirun ti so pe akori orin merin lo wa ninu rekoodu tuntun ohun, awon naa niwony; At last o ja sope, Jesus we worship you, Akiikitan Arugbo ojo, Nigeria si maa Dara.
Aago meta osan lo so pee to ohun yoo bere, nibi ti awon olorin emi lolokan-o-jokan naa yoo ti peju pese lati forin emi yin Olorun, tawon ololufee yoo si gbadun ara won daadaa pelu.

Post a Comment

0 Comments