Ariwo ikunle abiyamo o lo gba enu awon eeyan kan laduugbo
Ebute Meta lowuro oni, ojo Aje Monde nigba ti osise kansu, Rafiu Gbadamosi lu
magun lara iyawo oniyawo, to si se bee gbona orun lo.
Ni nnkan bi aago mokanla aaro ni ariwo buruku yii so lagbegbe
Cementary Street ni Ebute Meta, l’Ekoo nigba ti okunrin naa sadeede takiti lori
obinrin ti won jo n se ere wamo-wamo, to si se bee dero orun. Won ni o pe tawon
mejeeji ti jo maa n sere wamowamo kiri, ti oko obinrin yii si maa n kilo fun
iyawo e, ki kinni ohun too yiwo mo won lowo, nileetura kan ti won so pe won gbe
ara won lo lagbegbe Evans Square, ti iyawo oniyawo si salo ni tie ni kete ti
Rafiu ti je Olorun ni pe.
Ohun ta a gbo ni pe, ariwo ti iyawo e n pa ni kete tisele
ohun waye ni pe, oun kilo fun oko oun to ko ye tele iyawo oniyawo kiri. Won
lobinrin yii so pe, oko obinrin to gbe lo sile itura yii ti kilo fun un ko fi
iyawo oun sile, sugbon ti oko e ko gbo.
Omo meta ni won so pe Rafiu bi, ijoba ibile kan ni Ebute Meta
ni won so pe o ti n sise, bee ni won so pe o sese le ni omo ogoji odun ni, ati pe
omo Ijebu Itele ni paapaa.
Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jo, oku okunrin yii si wa nile,
lagbegbe Ebute Meta, bee lomobinrin ti won jo sere wamowamo yii ti salo ni tie.
A gbiyanju lati ba iyawo e soro, ero repete to pe le e lori
ko je ki o le so ohunkohun.
Won ni okunrin naa si ni mama laye, ati pe ni nnkan bi ojo
meloo kan seyin lo se akanse adura fun baba re to doloogbe ni nnkan bi ogun odun
seyin.
0 Comments