Oludije fun ipo gomina, Seneto Iyiola Omisore labe asia egbe
oselu SDP ninu ibo to waye nipinle Osun ni Satide, ojo Abameta to koja yii ti
di ojulowo oloselu bayii ti gbogbo awon oloselu egbe e n wa kiri.
Bi awon egbe oselu APC se n wa okunrin oloselu yii, to ti
figba kan se igbakeji gomina ri, bee lawon PDP paapaa ko je ko gbadun niseju
kan, nise lawon egbe mejeeji yii n be e gidigidi, ti won si n fi orisirisi ipo
be e paapaa.
Ohun kan pataki ti won n be Omisore fun ni bi yoo se darapo
mo won, ti atundi ibo to fe waye ni Tosde to n bo yii, yoo senuure fun won.
Okan lara awon oloselu to sepade pelu Seneto ohun loni-in ni
Aare ile igbimo asofin Seneto Bukola Saraki. Ninu oro ti Bukola Saraki so fawon
oniroyin ni kete to kuro lodo Omisore ni pe, “Ipade to so eso rere la jo se pelu
Seneto Omisore, bee la nigbagbo wi pe awa egbe oselu PDP la o jawe olubori.
Ipade ohun si n te siwaju, nitori a tun n bo lola, a si nigbagbo pe yoo yori si
rere fun egbe wa.”
Iyiola Omisore ninu oro tie naa so pe, loooto lawon egbe
oselu mejeeji, APC ati PDP ti n wa oun kiri bayii, bakan naa lo fi kun un pe,
egbe oselu SDP toun dije loruko e setan lati sise papo pelu eyikeyi to ba setan
lati tele akosile erongba rere ti egbe naa ni fun araalu.
Te o ba gbagbe, ninu ibo to waye lojo Satide, egbe oselu PDP
ti Ademola Adeleke dije loruko e lo n le iwaju pelu ibo egberun lona igba-o-le-erinle-laaodota ati ibo
mokandin-leedegbinrin (254,699), nigba ti
Isiaka Oyetola toun dije labe asia egbe oselu APC ni tie ni ibo egberun
lona igba-o-le-erin-le-laaodota ati ibo oodunrun-o-le-marun-un-din-laadota
(254,345).
Seneto Iyiola Omisore, to
dije loruko egbe oselu SDP, to siketa ninu idije ohun pelu ibo egberun lona
eji-din-ni-aadoje-o-le-mokandinlaadota (128,049).
Ni bayii ti ajo INEC ti
kede wi pe atundi ibo yoo waye lojo Tosde to n bo ni awon agbegbe yii, Orolu,
Osogbo ati Ife, gbogbo ona lawon oloselu mejeeji yii, APC ati PDP n wa lati fi
fa oju Omisore mora, ki ibo e le kun tiwon, ki won baa le jawe olubori ninu
atundi ibo naa.
0 Comments