GBAJUMO

SEYI MICHAEL FE TU MEWAA WO NI LASCOFIS L’EKOO


Loni-in Fraide yii ni gbajumo olorin juju nni yoo tun tu mewaa wo nileetura LASCOFIS, eyi to wa ni WEMCO Road ni Ogba, Ikeja, l’Ekoo.
Aago mefa irole ni okunrin gbajumo olorin juju yii so pe faaji yoo ti bere, eyi ti won pe ni LASCOFIS Entertainment, iyen faaji opin ose lagbo LASCOFIS.
Ninu oro okunrin onijuju yii lo ti so pe, “Ere ti a fe se fun awon ololufe wa loni-in yoo tun yato, idi ni pe lojoojumo ni Seyi Michael fi n gba ona tuntun yo. Oluwa ko fi wa sile nigba kan, fun idi eyi, lotun-lotun lo n fun wa larada, faaji ti awon eeyan ko jegbadun e ri ni won yoo ba pade loni-in, nitori ka korin to mogbon dani, tiwa ni o, ati pe ki a fun awon eeyan ni ilu alujo, ti ko siru e nigboro, gbogbo eyi pata ni Olorun fi ke wa. E wa, e je ka jo gbadun ara wa daadaa.”
Lara awon olorin juju ti won n se daadaa lasiko yii ni Seyi Michael n se, bee opo rekoodu loun naa ti se, ti won si mo on daadaa laarin awon ololufe orin juju atawon ti won ko le ma gbo orin to ba ti mogbon dani.


Post a Comment

0 Comments