GBAJUMO

SHE BABY KO AWON OSERE NLA NLA LO SI LONDON *SINIMA KAN NI WON LO YA NIBE


Niluu London lohun-un ni gbajumo osere tiata nni, Seyi Ariyo, eni tawon eeyan tun mo si She Baby atawon gbajumo osere bi Femi Adebayo, Laide Bakare atawon mi-in ti pade, nibe gan-an ni won ti ya sinima ti won pe akole e ni Dark.
Itan inu sinima yii da lori toko-taya kan, Mofe ati oko e. Omoluabi ponbele ni Mofe, eni to mo itoju oko ni, bee lo soro fun enikeni lati so pe, nibi kan bayii ni Mofe ku si, sugbon pelu iwa rere to ni yii, lojiji ni wahala deba igbeyawo e, ti aarin oun ati oko e, Femi Adebayo si bere si daru gudu.
Ninu akitiyan e lati satunse sibi to ti kuna ninu igbeyawo e, gbogbo ona to ye pata lo to, bee lo fadura jagun pelu, sugbon ibeere kan to wa jeyo ni pe, nje oko e setan lati foriji i bi, ki ajosepo aladun won si tun te siwaju, gbogbo e pata le o ba pade ninu sinima aladun yii, ti won pe akole e ni Dark.
Lara awon osere ti won kopa ninu e ni Femi Adebayo, Seyi Ariyo, iyen She-Baby; Laide Bakare, Kenny George; Leye Adeshile Kuti atawon osere pataki mi-in.
Okan pataki ninu awon osereb tiata Yoruba ti won n se daadaa nidii ise ohun nu Seyi Ariyo, iyen She Baby je. Yato si pe arewa obinrin yii je osere tiata, bee lo tun korin, tawon eeyan si mo on daadaa pelu ninu orin igbalode, iyen Hip-hop kaakiri Nigeria ati loke okun.

Post a Comment

0 Comments