![]() |
Abdul-Aziz Yari, gomina ipinle Zamfara |
Nibi ipade kan tawon gomina se lana-an, Ojoru
ni won ti fenuko wi pe yoo soro fun opolopo ipinle lati maa san egberun lona
ogbon naira gege bi owo osu osise to kere julo, iyen tawon ko ba fe kogba sile.
Niluu Abuja nipade ohun ti waye, ninu eyi ti
gomina ipinle Zamfara, Abdul-Aziz Yari, eni ti se alaga won ti dari e.
Deede aago mejo ale ni ipade ohun bere, ninu
eyi ti awon gomina wonyi ti wa nikale; gomina
ipinle Eko, Akwa Ibom, Zamfara, Benue atawon
mi-in pelu.
Leyin ti won pari ipade won, ohun ti alaga won so, iyen Abdulaziz
Yari, gomina Zamfara ni pe, awon ti gbe igbimo mi-in kale to maa lo
yoju si Aare Muhammed Buhari, nitori pe pupo ninu awon ipinle to wa lorile-ede
yii ni ko ni i le san owo ohun, ayafi ipinle Eko nikan, latari opolopo ona ti
ipinle naa n gba ri owo pa sapo ikowosi e.
O ni, pupo ninu awon ipinle ni yoo pada di onigbese, to si
see se ki won kogba sile, ti won ba fi le dagbale sisan iru owo bee.
Ni bayii ti won ti gbe igbimo mi-in kale, awon yen ni won
yoo yoju si Aare Muhammed Buhari lori ona ti won yoo gbe oro ohun gba, ko too
tun dogun-dode.
Sa o, bi oro yii ko se ni i da wahala nla sile laarin egbe
osise ati ijoba, eyi to see se ko mu iyanselodi olojo gbooro wa, iyen gan-an lo
n se opo eeyan ni kayeefi bayii.
0 Comments