Bi egbe osise ile wa se n mura
lati bere iyanselodi lojo Tusde, ose to n bo yii, iroyin to gba igboro kan bayii ni pe ajo
NUPENG, iyen awon osise agbepo-ka ti so pe awon naa yoo darapo mo iyanselodi,
eyi ti won so pe o see se ki o fa owongogo epo lose to n bo
Bo tile je pe ijoba apapo ti
gbe oro ohun lo si ile-ejo, National Industrial Court, nibi ti won ti fofin de
egbe awon osise wi pe won ko gbodo da wahala iyanselodi sile, sibe ajo NLC atawon
eka won mi-in ti so pe; o ti di dandan ki awon bere iyanselodi ohun, nitori ko
seni to fun awon niwee kankan wi pe, ohun ti ile ejo so ree.
Bi won se wa n mura e yii, bee
lawon NUPENG naa ti so pe awon naa yoo darapo mo won. Eyi gan-an lo mu awon
awon eeyan maa so pe, owongogo epo yoo sele, niwon igba ti awon osise agbe-epo
kiri ko ba ti sise, epo yoo won laarin ilu, bee ni ariwo ko-sepo-ko sepo yoo wa
gba igboro kan!
Eni to je aare fun egbe NUPENG,
Omooba Akporeha ti so pe, niwon igba ti awon naa ti je ogunna gbongbo lara egbe
osise orile-ede yii, o ti di dandan ki awon kopa, bee naa lo fi kun un wi pe,
ko ti i de setii igbo awon wi pe ile ejo kan ti pase pe iyanselodi kankan ko
gbodo waye.
Te o ba gbagbe, ohun ti are
egbe awon osise, Ogbeni Ayuba Wabba atawon akegbe e n ba ijoba apapo fa ni bi
won yoo se so owo osu osise to kere ju di egberun lona ogbon naira (N30,000). Nigba
ti ijoba ni tie so pe oun ko le san ju egberun lona mejilelogun naira ati
eedegbeta naira (N22,500) lo.
Nibi ti oro ti di iyan laarin
won niyen, ohun ti egbe awon osise, NLC, TUC atawon eka mi-in si n so ni pe, Tusde
to n bo yii lawon setan lati ba ijoba na an tan bii owo, nibi ti oro yii yoo
yori si, oju ree, iran ree.
0 Comments