Esun ti won fi kan an ni pe okunrin naa fe ba omoleewe kan,
Monica Osagie sun, nitori tiyen ni ko
fun oun ni maaki, ki oun le yege idanwo oun.
Ohun ti a gbo ni pe, ti won ba fi le gbe eeyan lo sile-ejo
lori iru esun bee, ti adajo ba si so pe eeyan jebi peren, ewon odun meje ni tohun
yoo fi gbara.
Saaju asiko yii ni Yunifasiti Ife ti le okunrin naa, Ojogbon
Richard Akindele lenu ise lori esun ti won fi kan ohun, bee ni won tun ti so pe
o ti di dandan ko lo kawo ponyin rojo niwaju adajo l’Osogbo.
Te o ba gbagbe, nibere odun yii ni fonran kan gba igboro
kan, nibi ti Ojogbon nla yii ati okan lara awon akekoo iwe agba, (MBA) ti jo n
soro lori foonu lori bi won yoo se pade, ti won yoo gbadun ara won daadaa. Ninu
fonran ohun gan-an ni omoleewe ti n beere fun maaki, ti ojogbon ni tie si n
beere fun ibasun, a-se-lera-lera bii eemarun-un, ti omoleewe yoo si gba maaki
to dara ju.
Bi fonran yii se gba igboro kan lawuyewuye nla ti gbalu, ki
oloju si too se e, Yunifasiti Obafemi Awolowo n’Ile-Ife naa ti bere iwadii won,
abalo-babo e, nni won ba so pe ki oga onimo nla ninu isiro owo yii maa lo sile,
won ni ko fi ogba ileewe ohun sile fawon, nitori oniwa ibaje, ti ko ye niru
awujo bee lokunrin ohun n se. Sugbon ko tan sibe o, ile-ejo naa tun ti n duro
de e bayii, lati gba idajo to ye.
Sa o, saaju asiko yii, iyen nigba ti Ojogbon Akindele da esi
leta ti ileewe ohun ko si i pada lati salaye ohun to mo nipa esun ti won fi kan
an lo ti so pe loooto loun mo obinrin naa daadaa, ati pe ibasun ti oun n beere
fun, ki i se latowo oun, bikose pe omo naa lo n ti ara e mo oun lorun.
Ninu awijare okunrin onimo nla yii naa lo ti so pe, “Lati
odun to koja, ninu osu kokanla odun 2017 lomobinrin yii ti n fi ibalopo le mi
kiri, bo se n pe mi lori foonu loganjo
oru, bee lo maa n pe mi lale, koda, o ti ya foto abe e ri, to fi sowo si mi
lori foonu mi, eyi ti mo ni gbogbo e pata lowo.
Okunrin yii fi kun un pe ibasun ti oun so pe oun yoo ba a se
lemaarun-un, o ni oun fi gba ara oun sile ni, nitori obinrin yii atawon okunri
kan ti n lepa emi oun kiri, ti oun ko ba si se bii eni gba ohun to fe, o se see
ko seku ojiji pa oun.
Akindele so pe, ohun to buru ju nibe ni pe, nise lomo naa
yara ju oun lo, to fi dogbon gba ohun oun sile, tiyen si dohun tawon eeyan n
pin kiri ero ayelujara.
Bo tile je pe o ko gbogbo alaye yii pale, sibe Yunifasiti
Ife ti le e danu, bee ni won so pe ko si ohun kan bayii ti awon le se fun
omobinrin naa, nitori ki i se omoleewe naa mo, ati pe eko to wa gba paapaa, ko
ka a yanju, to fi keru e ti ko wa mo.
0 Comments