GBAJUMO

WON TI SUNKU MAMA AJIGIJAGA ONITIATA


Tebi t’ara atawon ore ni won peju pese laipe yii nigba ti won sinku Oloogbe Madam Olufunmilayo Ayoka, eni ti se iya gbajumo osere tiata nni, Mufutau Sanni, to doloogbe lojosi.
Ninu atejade ti omo Oloogbe ohun fi sowo si wa, Abdul-Rasheed, okan lara eni ti i se gbajumo olorin fuji lo ti so pe, “Eni ogorun-un (100) odun ni mama, ki won too jade laye lojo keedogun osu kokanla yii.”
Fraide ojo kerindinlogun osu yii ni won seto isinku mama ohun ni Rescue The Perishing Church, Eredo, Yewa South, nipinle Ogun.
Opo omo ati omo omo lo gbeyin Oloogbe Olufunmilayo Ayoka Quadri eni tawon eeyan tun mo si Iya Oniru, nigba aye e.
Lara awon omo iya yii ni Oloogbe Mufutau Sanni, gbajumo osere tiata nigba aye e, tawon eeyan si mo daadaa si Ajigijaga, lara awon omo e naa ni Arabinrin Safuriat Ajoke,  Monsurat ati Monsuru Kodir.

Post a Comment

0 Comments