Okan lara awon olorin esin Islam ni Alhaja Hafsat Opeyemi
Ade-Adele, eni tawon eeyan tun mo si Alujo Adinni. Laipe yii lo ba wa soro lori
idi ti kii fi ba won se rekoodu alasepo ati ohun to mu ni pataki gege bi olorin
Islam.
Alhaja Hafsat Opeyemi ninu oro e ti so pe, “Odun keedogbon
ree ti mo ti n korin, a du wi pe, eni iwaju lawa naa nidii ise yii. Ohun to si
se pataki fun wa nidii e ko ju bi a o se lo o lati fi se waasi, lati fi to awon
eeyan sona, ki a si fi gbe ogo Islam ga.”
Nigba to n soro nipa rekoodu to ti se, o ni, “Rekoodu meta
otooto ni mo ti se, akoko ni Takuula, eyi to tumo si E beru Olorun, ikeji ni
Ile oko, iketa ni Women Slavery.
emi ki i ba won se rekoodu alajosepo, eyi ti won maa n pe ni
Duet tabi Collabo. Ki i se pe mo korira awon to n se o, tabi lodi si won, o kan
je pe mo nigbagbo ninu sise eyi ti enikan soso maa dase gege bo ti se wa latiberepepe, ki n si se e daadaa,
ninu eyi ta a ti wulo fun esin ti a n polongo e.
“Ohun pataki ti orin temi da le lori ni waasi sise, ati ona
kan pataki ti eeyan le gba kekoo nipa ibasepo pelu omolakeji pelu alaafia.
Gbajumo olorin yii, eni ti se iyawo Lawori, okan lara awon osere tiata Yoruba nigba to n salaye lori bo se bere orin Islam so pe, “Mo bere
orin mi latodo Alhaji Sheik Tiajni Omotoso, baba daadaa ni won, ki Olorun tubo
ba mi se alekun oore gbogbo fun won. Odun 1993 gan-an ni mo bere si tele won, n’Idimu
nijoba ibile Alimoso l’Ekoo. Opolopo eko to le mu eeyan jere ise yii ni won ko
mi, mo si dupe wi pe loni-in, laarin awon olorin esin Islam, Oluwa n se bebe
ninu aye tiwa naa.”
Siwaju si i, Alujo Adinni ti sapejuwo orin Islam gege bi ona
ola fun gbogbo eda, eyi to je atona oye nipa esin ati olukoni niwa omoluabi.
O ni, “Irufe orin ti a gbe dani, ise nla kan ni, ti a gbodo
mo ohun ti a n se nidii e. Idi niyi to fi se pataki fun awa ti a n korin Islam
lati je awokose gidi, ki ohun ti a n ko je orin rere ti yoo mu ilosiwaju ati
anfaani nla ba awon ololufe wa ti won n gbo orin wa.
“Igbagbo mi ni wi pe, orin ti ko le ti ni, bee ni yoo wa
laelae, ninu eyi ti awon to n bo yoo ti maa ri nnkan deba, ti yoo si wulo fun
won titi aye. Awa naa ba a laye ni, nitori e gan-an lo se se pataki fun wa lati
se e lona ti yoo fi maa te siwaju si i, ti ibaje kankan ko ni i kan an.”
Alujo Adinni ti wa fi da awon ololufe e loju wi pe laipe yii
ni won yoo ri ohun ara otun mi-in latowo oun, eyi ti yoo migboro titi.
0 Comments