Oludije fun ipo gomina nipinle Oyo, Oloye Adebayo Adelabu ti fi
awon omo ipinle Oyo ti won n gbe loke okun, paapaa niluu London lokan bale wi
pe oun setan lati sise po pelu won ni kete ti oun ba ti wole sipo gomina nipinle
Oyo lodun 2019.
Oloye Adelabu soro yii lopin ose lasiko to n ba awon omo egbe
oselu APC, eka ilu London soro lori foonu.
Ninu oro e naa lo ti salaye koko ise meje to fe gbe se nipinle
Oyo. Nibe naa lo ti beere fun iranlowo awon omo egbe oselu ohun lati satileyin
fun un ko le jawe olubori ninu ibo to n bo.
Adelabu fi kun oro e wi pe loooto loun mo ipa ribiribi ti awon omo
egbe oselu naa ti won wa loke okun le ko nipa ise idagbasoke eto oro aje ati
ilosiwaju orile-ede lapapo. Bee gege lo ti seleri wi pe ijoba oun setan lati
sise po pelu won; ninu eyi ti yoo fun awon naa lanfaani lati fi imo nla ti won
ni fi ran ijoba oun lowo ni kete ti won ba ti dibo yan oun nipinle Oyo.
Siwaju si i, o ti wa ro awon omo egbe oselu naa lati kopa manigbagbe
ninu eto ipolongo ibo, eyi to ti bere bayii, ki awon eeyan nigbara ati nigboro
ipinle Oyo le fibo won gbe oun wole lodun 2019.
Ninu oro alaga egbe oselu naa lorile-ede Geesi lohun-un, Ogbeni Kolawole
Saidu, ni tie ti seleri atileyin to gbopon lati owo awon omo egbe ohun fun oludije
ipo gomina labe asia egbe oselu APC nipinle Oyo.
Bakan naa ni awon eeyan meta, ti won je omo egbe oselu ohun, ti
awon naa kopa ninu idibo abele, sugbon ti won ko jawe olubori naa ti seleri
atileyin won fun oludije yii. Bee ni won so pe awon setan lati dari gbogbo atileyin
awon pata fun un ninu ibo ohun to n bo.
Siwaju si i, oga agba ileese to n maa n se igbelaruge fawon olorin
loke okun, iyen BNS Promotions, Arabinrin Dupe Okesanjo naa ti so pe oun setan
lati kun awon omo egbe oselu naa ti won wa ni United Kingdom lowo fun atileyin egbe
oselu APC, ki Adebayo Adelabu le jawe olubori.
Arabinrin Dupe fi kun oro e pe, “Mo setan lati lo owoja ileese
wa, gege bi amuludun lati fi gbarukuti eto ipolongo oludije fun ipo gomina
nipinle Oyo ni London nibi ati ni Nigeria, nibi ti opolopo awon ti a n se
igbelaruge fun wa; bee ni mo tun nigbagbo wi pe awon eeyan wa yoo tun ba awon
ebi, ara ati ore won; ti won wa nile soro, ti aseyori yoo si wa fun oludije wa ninu
ibo ohun lodun 2019.”
0 Comments