Pitimu lawon eeyan pe si
gbongan nla Mapo niluu Ibadan ipinle Oyo nigba ti Oloye Yetunde Babajide, oga
agba fun ileese YEFADOT ko awon eeyan e dewaju Olubadan, Oba Saliu Adetunji.
Ohun ti Iyalode Ojodu atawon eeyan
e, ti oruko won n je APC VOLUNTEERS SUPPORT GROUP for Buhari/Osibajo 2019, iyen
awon omo egbe oselu APC ti won n satlieyin fun ipada-sipo Aare Buhari ati
Igbakeji e, Yemi Osibajo lo se lodo Olubadan ko ju bi kabiyesi yoo se fowo si i,
ti awon eeyan Ibadan yoo si gbarukuti awon omo egbe oselu APC yii ki Buahri le
jawe olubori lodun to n bo.
Biba bii esu lawon ero pe, ti
kaluku won fe gbo ohun tuntun tawon eeyan yii fe so nipa Aare Muhammed Buhari,
bee ni Olubadan, Oba Saliu Adetunji paapaa wa nikale nigba ti Oloye Yetunde Babajide
ba gbogbo awon eeyan Ibadan soro.
Bee, oro ohun soju Iyaloja
Alimi, ti oju awon oloja naa pe, tawon onise owo paapaa si wa nikale paapaa.
Babajide ninu oro e so pe, ayipada rere lo ti
ba orile-ede yii ni kete ti Aare Muhammed Buhari ti gori oye. Ninu oro e naa lo
ti ro gbogbo awon omo ilu Ibadan atawon alejo ti won ti di omo onile lati gbiyanju
dibo won leekan si i fun Buhari ati Osibanjo ki mudun-mudun ijoba to n gbogun
ti iwa ibaje yii le tubo kari daadaa.
Siwaju si i, orisirisi awon ise
idagbasoke ilu, paapaa awon ohun ironilagbara ti ijoba Buhari se lati fopin si
ise ati iya to n ba awon omo orile-ede yii finra lo menuba.
Bakan naa lo fi kun un pe eto
eyawo ti wa fawon to ba mo nipa ise agbe daadaa atawon onise owo paapa. Bee
gege lo fi kun un pe eto eyawo naa ko nilo a n fi ile tabi dukia eni duro, ati
pe ki anfaani irufe ife mekunnu yii le te siwaju lo fi se pataki ki awon eeyan
tun fibo won gbe Buhari wole leekan si i.
Ninu oro Olubadan, Oba Adetunji
lo ti dupe lowo Iyalode Babajide, bee gege lawon oloja atawon onise owo seleri
atileyin won fun Buhari lodun to n bo ninu ibo gbogbo-gboo ohun.
Ni bayii, won ti fun Oloye
Monsurat Yetunde Babajide loye iya egbe awon oloja nipinle Oyo.
0 Comments