GBAJUMO

LEYIN ODUN MEEDOGUN, SHERIFATU OLUWA, OSERE TIATA TUN DOLOMO


Lara awon osere tiata Yoruba ti inu won n dun gidigidi lasiko yii ni Arabinrin Sherifat Oluwa, eni tawon eeyan tun mo si Queen. Obinrin arewa naa sese dolomo tuntun ni o.
Ilu Amerika lohun-un ni Queen bimo ohun si, nibe gan-an ni won ti so o loruko, ti die ninu awon osere egbe e si wa a debe lati ki i ku ayo omo tuntun.
Ninu oro e lasiko to ba Magasinni yii soro lati ohun lo ti so pe, “Ohun idunnu nla lo je fun mi wi pe, mo tun sabiyamo leekan si i. Se e kuku mo wi pe, akobi mi ko niyi, sugbon mo dupe lowo Olorun wi pe, nigba to tun wu mi ki n bimo, were bayii ni Olorun tun se e. Ope ni o, ki Olorun Eledumare ko tubo ba mi se e fun gbogbo awon eeyan pata ti awon naa n fe iru oore yii. Ki a ma paro, emi ni inu mi dun lasiko yii.”

O fi kun oro e wi pe, ogbonjo osu karun-un odun 2003 loun ti bimo gbeyin lasiko ti oun bi akobi oun to n je Oyinkansola.
Aamanee Eyitayo Tiwatope lo pe oruko e omo e tuntun, bee gege lo so pe oun ko setan lati so ohunkohun bayii nipa baba omo oun.


Post a Comment

0 Comments