GBAJUMO

'LOOOTO NI MO N JE SARAKI, SUGBON EMI KO BA WON TAN NI KWARA O'


Lara awon olorin esin Islam ti won n se daadaa loni-in, okan pataki ni Alhaji Saheed Olorunkemi, eni tawon eeyan tun mo si Saraki. Omo Imaamu ilu nla kan ni, bee loun naa dangajia daadaa ninu imo kewu ati esin Islam.
Ti a ba n so nipa bo se bere orin esin Islam, Modiu gan-an lo fi bere, iyen orin kan ti awon omo Ijo Tijaniyyah ati Qudriyyah loju ona Sufi maa n ko daadaa, paapaa lasiko ti won ba n sayeye Anobi Muhammed. Orin yii lo fi bere, tawon eeyan si mo on daadaa pelu e.

Were bayii ni o, nigba to si ya, bi Saraki naa se tun fi awon orin mi-in kun un niyen, toun naa si ti gberegejige ta a ba n so nipa orin esin Islam loni-in.
Saraki ti ba wa soro, bi alaye ohun to so se lo ree:  
Bi mo se bere orin gan-an
Ti mo ba n so nipa bi mo se bere, o se die o, bee lo to ojo meta. Ninu ijo wa ni mo ti koko bere orin, Modiu, iyen orin iyin Anobi ni mo fi bere, bee lawon eeyan mo mi daadaa.
Asakiru lawon eeyan tun maa n pe mi, ni gbogbo igba ta a ba ti n sayeye ojoobi Anobi Muhammed, emi ni won maa n pe lati wa se Modiu, ti Olorun si fi ro mi lorun daadaa.
Ninu irin-ajo ohun ni mo ti lo si ile Hausa, ijo Ansaruuden lo gbe mi dohun-un, oye Noibul Imam ni egbe Ansarudeen Society fun mi, ilu kan to n je Gwada ni Minna, ipinle Niger gan-an ni.
Ilu yen naa ni mo wa ti mo ti bere si ni ro o bi mo se maa so ise orin di ohun ti maa koju mo gidi, ti yoo si tibe gbooro daadaa.
Emi o kose labe eni kankan

Emi o kose labe enikeni o, gege bi mo se so, ninu ijo Tijanniyah ni mo ti bere gege bi Asakiru to maa n se Modiu, imo kewu ti mo ni pelu ohun to ran mi lowo daadaa. Nigba ti mo si maa mu ise orin ni okunkundun, irorun lo ba de pelu iriri ti mo ti ni tele.
Bo tile je pe mo ti lebun orin tele, sibe, o ni eeyan pataki kan ti mo n wo gege bi awokose. Alhaji Ibrahim Labaeka ni o. Se e mo pe orin sikiri lawon naa fi bere, ko too di pe o bureke, ti won si di ninla loni-in.   
Mo tun ni enikan toun naa se bebe fun mi lasiko igba ti mo wa nile Hausa, Abdul-Waheed Aremo loruko eni ti mo n so. Imoran olowo-iyebiye lo fun mi, awon gan-an ni won so pe to ba je pe orin ni mo fe maa ko, ki n fi ile Hausa sile, ki n pada saarin awon eeyan mi nile Yoruba, bi mo se digba-dagbon mi niyen o, ti mo pada si ilu mi.
Bi mo se pada si ilu mi niyen, ti mo n korin, bee ni Alhaji Waheed Aremo naa ni ipa nla ti won ko. Ti won ba ti ni ode ere, a jo maa n lo ni, bee ni won maa n fun emi naa ni anfaani lati korin, bo se di pe awon eeyan bere si ni ri mi niyen, ti won tun n ri ona ara mi-in ti mo n forin da, yato si orin Modiu ati Asikiri ti won mo mo mi tele. Bi mo se bere were niyen o, ko si pe pupo ti Olorun fi gbadura mi.
Emi ko tan mo Saraki o…

Opolopo eeyan lo maa n ro wi pe mo ba awon Saraki tan niluu Ilorin. Rara o, Saraki ti mo n je, alaje lasan ni. Raji Olorunkemi gan-an loruko baba mi. Imaamu agba ni won. Oluko mi kan lo so mi loruko yen ni ile keu, Ustaz Qozim loruko won. Nigba ti mo wa nile-keu, ti gbogbo awon akegbe mi ba ra nnkan, ohun ti emi maa n ra maa n saaba yato die si tiwon. Titi to fi dori ounje ti emi atawon egbe mi ba ra nigba yen. Iyen gan-an ni oluko yen ri, bo se bere si ni pe mi ni saraki niyen. O ni saraki ni mi laarin awon elegbe mi yooku, itumo eyi ni pe, awon nnkan gbajumo to yato ni mo maa n se laarin awon yooku mi..
Ohun to mu mi yato sawon olorin yooku
Alfa ni mi, bee ni mo nimo keu ati esin Islam daadaa. Ohun to fa a ni pe ninu molebi mi, gbogbo wa pata la keu daadaa, ti oro esin si ye wa yekeyeke, titi to fi dori awon obinrin wa pelu, Alfa ni gbogbo wa nile wa, bee omo Imaamu agba ni wa. Ebun orin ti mo ni loni-in, mo le so pe ara baba mi ni mo ti ri i, nitori pe eeyan nla kan ni won ti Olorun fun ni opolopo ebun, lara e naa ni orin kiko, sugbon awon ko fi sise se ni tiwon.
Nigba ti mo bere si ni korin, won fowo si i, bee ni won si n fun mi ni aduroti to peye.
Imo keu ati esin Islam ti mo ni ko sai ni ipa nla to n ko ninu orin ti mo n ko. Se mo so pe mi o kan sadeede bere ise orin, Modiu ni mo mo fi bere, nigba to ya ni mo so o di asikiri, ko too di pe a so o di ninla ti awon eeyan bêre si pe wa kaakiri Nigeria ati lawon orile-ede mi-in.

Gege bi eni to wa lojuna Sufi ti Sheik Ahmad Tijani, opolopo oye lo ye ki a fi ye awon eeyan nipa esin ti a n se ati oju ona ti a n to. Mo wa ri i pe orin je ohun kan pataki ti awon eeyan fe kariaye, nibe ni mo ti ro o wi pe o maa dara ti mo ba le maa fi orin mi jise, ki n si maa fi se waasi oro Olorun.
Ohun ti eleyii tumo si ni pe, awon eeyan yoo lanfaani lati gbo orin aladun to dun mo won ninu, bee ni won yoo gbo ilu gidi ti won a si gbadun ara won daadaa, ti ko ni i je eyi ti a mu eeyan kolu ofin Olorun. Ninu e naa ni won yoo ti gbo waasi, iyen oro Olorun. Mo n fi oko kan pa aimoye eye ni o, bee gan-an loro emi ati orin se je.  

Rekoodu ti mo ti se…
Omo ilu Ejigbo ni mi nipinle Osun. Yato si rekoodu temi gan-an, orisirisi rekoodu alasepo ni mo ti se pelu awon eeyan. Lara e ni; Aye talika 1&2, Talore, Akunleyan ati rekoodu temi gan-an ti mo da se ti mo pe akole e ni Ireti.
Ojo kokanla osu keta odun yii ni mo se ikojade e niluu Osogbo, awon eeyan pataki lorisirisi lo ba mi debe.
A dupe wi pe a ti lo siluu Mecaa fun ise hajj, bee la se gbogbo ise to ye ka se nibe.
Ni kete ti mo pada de, awon ololufe mi; Saraky Fans Club ni Nigeria nibi gbe eto kan kale lati fi ki mi kaabo, ilu mi ni Ejigbo, nipinle Osun lati se e.
Bakan naa lawon ololufe mi ni Abidjan naa se tiwon fun mi, iyen ere ikinni-kaabo, ileese kan, DENTELLECI BNAF ati MONSHALLAH CLUB ABIDJAN lo sagbateru e.

Ohun ti mo ri pelu ohun ti won se yii ni pe, ife alailegbe ni won ni si mi, bee lemi naa n fojoojumo dupe lowo Olorun lori oore nla yii.
Erongba mi fun ojo iwaju nidii orin
Ohun to wu mi julo nidii ise orin yii ni bi awon eeyan ti won n gbo wa yoo se maa ri eko nla ko latari orin wa ti won n gbo. O ye ki a je olutona fun awon eeyan ni, latari ise wa ati isesi wa. Orin wa lo gbodo maa kun fun waasi, bee lawa naa gbodo fi ife ba ara wa lo, ki a si ni in lokan lati maa seranlowo fun awon to ba n bo leyin. Olorun nikan lo ni okiki lodo, oun lo le so eeyan di irawo nla.
Yato si eyi, a gbodo je ki gbogbo aye mo wi pe esin alaafia, esin irorun ni Islam ti a n se. Ise po fun awa olorin o, nitori mo nigbagbo wi pe lara ojuse wa ni lati ko alaafia ba ilu latara orin wa, ki a si je ki awon eeyan tubo ni imo kikun nipa esin Islam ati ojuse wa gege bi musulumi sira wa ati si awon eniyan yooku gbogbo layika wa, lorile-ede wa ati kaakiri agbaye. Islam ki i se esin jagidijagan, fun idi eyi, o ye ki awa naa maa polongo e, ki a si je Musulumi daadaa to gba Olorun gbo, to si fi ife ooto tele Anobi Muhammed.


Post a Comment

0 Comments