Gbogbo
eto lo ti pari bayii lori ayeye onibeji ti gbajumo olorin esin Islam nni, Queen
Ambassador Mariam Akiiki Oloriire fe se l’Ekoo.
Ola,
Tusde ojo Isegun ni eto ohun yoo bere, ti yoo si kadii e nile lojo Abameta
Satide to n bo. Ayeye to pe ni onibeji yii, ninu e ni Mariam Akiiki yoo ti se
ifilole egbe kan to pe ni Queen Ambassador Akiki & Friends' Forum, eyi to
tumo si egbe Mariam Akiiki atawon ore e. Yato si eyi, bakan naa lo tun fe fun
awon ololufe e ni ami eye pelu.
Ninu
oro e lo ti so pe ola ojo Isegun leto ohun yoo bere, nibi ti awon yoo ti lo
sile awon omo alainiyaa lati lo fun won lebun, ti awon yoo tun ba won sere
pelu.
L’Ojoru,
Wesde ni gbajumo olorin Islam yii yoo ko awon omo egbe e atawon ololufe e sodi
lo sileewe St. Michael Primary School, iyen ile eko pamari to ti kekoo jade
lopo odun seyin. Ojobo ose yii naa ni won yoo lo sodo awon oba alaye kan, ti
won yoo tun fi ese kan de odo alaga ijoba ibile Ojo lati lo se baba ke e pe.
Lara
eto ti won tun ni naa ni irun Jimoh ti won yoo darapo mo gbogbo Musulumi aye
lati ki lojo Eti, Fraide ose yii ni Mosalasi Ojo Central Mosque, l’Ekoo.
Satide,
ojo Abameta ni asekagba eto ohun yoo waye nibi ti won yoo ti ifilole egbe Queen
Ambassador Mariam Akiki atawon ore e, bee ni won yoo tun fun awon eeyan pataki lami
eye lojo naa ni gbongan nla Ojo Town Hall, niluu Ekoo.
Mariam Akiiki
ninu oro e ti so pe, “O se die ti awa naa ti n ba a bo, a dupe lowo gbogbo
aawon ololufe wa ti won duro tiwa, ti ohun gbogbo fi n lo deede. Idi niyen, ti
a se fe fun awon eeyan pataki yii ni ami eye lati le fi se koriya fun won. Se
yinniyinni ki eni le se mi-in. Bakan naa la setan lati se ifilole egbe awon
ololufe wa, ti oruko egbe naa n je Queen Ambassador Akiki & Friends' Forum.
0 Comments