![]() |
Alayeluwa, Oba Fatai Aromire Ojora |
Ojo kin-in ni osu kin-in-ni
odun yii, lasiko tawon eeyan n sajoyo odun tuntun, ojo yen gan-an ni Kabiesi,
Oba Abdul Fatai Aremu Aromire, Ojora ti ilu Eko fe sayeye nla.
Ojo yii gan-an ni ojoobi
Kabiesi, nibi tawon eeyan yoo ti peju pese si Iga Oba lati ba Kabiyesi seye
nla. Bee gege ni Ojora yoo foye nla da awon eeyan pataki, ti won ti mu
idagbasoke orisirisi ba ilu ohun ati awujo lapapo lola lojo naa.
Okan lara awon omo Kabiesi to
ba wa soro, Omooba-binrin Adewunmi Ojora, Iyalode Onibaba niluu Ajegunle Apapa l’Ekoo
sapejuwe Kabiesi gege bi ori apesin ti ife ilu e atawon eeyan ibe je logun. O
ni, “Bi won ti se je baba mi, opo eko ni mo ko lara won, eyi ti o maa n je ohun
iwuri fun mi lopo igba, bee ti won ba n so nipa ki eeyan je omoluabi, ko tun
maa huwa rere, lara eko gidi ti mo ko lara won niyen, ki Olorun tubo je ki won
pe fun wa, bee ni mo gbadura fawon oloye tuntun naa wi pe, asiko ti won je e
yii, ilosiwaju nla ni yoo mu ba igbesi aye won, ile Ijora ati ipinle Eko
lapapo.”
![]() |
Musiliu Haruna-Ishola Alapala |
Lojo ayajo odun tuntun ti eto
ohun yoo waye, won ti so pe pepeye yoo ponmo niluu Ijora ti eto ohun ti fe
waye, nibi ti Kabiesi yoo ti dupe ojoobi tuntun, tawon eeyan ilu e naa yoo si
ba a sajoyo nla pelu orin ati ilu.
Gbajumo olorin apala nni,
Musiliu Babatunde Haruna-Ishola ni yoo so gongo silu, bee lawon eeyan yoo
lanfaani gidi lati gbo orin ati ilu apala lorisirisi.
0 Comments