Nitori awuyewuye to n migboro
titi nipa eni to da orin fuji sile, okan lara awon eso agbofinro ile wa, to n
sise pelu ileese olopaa, Alhaji Adeyinka Ishola, eni tawon eeyan tun mo si
Askari to-n-ko-fuji ti gbe rekoodu kan jade lati fopin si awuyewuye ohun.
Ninu rekoodu e tuntun
to pe akole e ni Explosion ni Askari ti fidi e mule wi pe Alhaji Sikiru Ayinde
Barrister gan-an lo da orin fuji sile, ati pe fuja ati fuji iyato wa nibe
daadaa. Bee lo ti so pe, ninu rekoodu tuntun yii gan-an lawon ololufe orin
fuji, atawon ti oro kan pata yoo ti gbo ekunrere alaye lori bi orin fuji ati bi
itan e se je gan-an.
Siwaju si i, Askari to
n ko fuji ti so pe, orisirisi orin mefa lo wa ninu rekoodu ohun, ninu eyi ti
oun ti ke si ijoba apapo lati mojuto oro awon olopaa ki awon agbofinro naa le
sise won bii ise, ki awon eeyan awujo paapaa naa le janfaani eto aabo to peye.
Ni kete to pari ise
lori rekoodu tuntun yii lo se ikojade e nileetura Blue Sea Lounge, lojuna
Akilo, Ogba, l’Ekoo, lojo kokanla osu kokanla odun yii, ninu eyi ti awon eeyan
pataki laarin awujo ti peju-pese sibe. Lara won ni Arabinrin Yetunde Longe,
okan lara awon oga agba nileese olopaa l’Ekoo. Awon mi-in tun ni oludije fun ipo
asoju-sofin labe asia egbe oselu PDP, Onarebu Lanre Osundairo atawon mi-in bii Hon.
Benjamin Osundairo; Hon. Agunbiade latinu egbe oselu APC nijoba ibile Ikeja l’Ekoo.
Bawon eeyan yii se wa
nibe, bee lawon legbelegbe paapaa wa, lara awon ni egbe awon olorin fuji, iyen
FUMAN, PMAN, Alhaji Omooba Adetoro, eni ti se olori awon awako taksi l’Ekoo
atawon omo egbe e.
Lara awon olorin ti
won fi orin aladun da awon eeyan laraya lojo naa ni Alhaji Musibau Alani,
Alhaji Bukola Alayande, eni tawon eeyan tun mo si Ere Asalatu atawon mi-in
lolokan-o-jokan.
Ninu oro Alhaji Ishola
Adeyinka, lo ti so pe, “O se pataki ki a je ki awon eeyan mo bi itan fuji se je
gan-an. Rekoodu tuntun yii wa se atunse ni, bee ni yoo fopin si awuyewuye to
tun fe maa sele bayii, paapaa lori eni ta a le pe ni oludasile orin fuji.
“Ninu rekoodu tuntun
yii ti mo pe akole e ni Explosion lawon eeyan yoo ti gbo winrirnin. Bee ni
alaye wa lori "Fuji ati Fuja ", bee ko si bi a se fe pitan orin fuji
ti enikeni gbodo yowo Alhaji Sikiru Ayinde Barrister sile, kin ni ipa Oloogbe
yii, gbogbo e pata lo wa ninu awo orin tuntun ohun.”
Ileese Dam J Music & Film lo gbe rekoodu
to kun fun opo tungba ati alujo lorisiri yii jade, bee ni orin ohun tun kun fun
ogbon pelu oye.
Oga agba patapata fun
gbogbo awon to n korin fuji, iyen The Inspector General of Fuji gege bi awon
ololufe Askari to n ko fuji se maa n pe e ti so pe, oun kanle se odidi orin kan
ninu awo tuntun yii lori itoju awon olopaa, ki eto aabo to peye le wa fun ateru
atomo.
O ni, “Ti ijoba apapo
ba toju awon olopaa daadaa, o daju wi pe awa olopaa naa yoo sise wa bii ise, ti
ojuse wa gege bi eso alaabo ko si ni i yinge rara laarin ilu.”
0 Comments