GBAJUMO

O MA SE O! AWON ASOFIN HO LE BUHARI LORI *BI WON SE N PE E LOLE NI WON SO PE ONIRO NLA NI


Nile igbimo asofin nisele ohun ti waye lasiko ti Aare orile-ede yii, Muhammed Buhari n soro niwaju awon asofin lori eto isuna owo. Bi okunrin omo Hausa yii se menuba awon aseyori e ni ariwo buruku so, bi awon kan se n pe e lole, lawon mi-in n pe e ni opuro, ti ariwo gee si so nile asofin.
Bi awon asofin yii se n ko si Buhari lenu lopo igba ti won ko je ki o soro e dele, ni gbogbo igba to ba ti menuba aseyori kan ti ijoba e se, bee lawon awon asofin a gbe ariwo, ti won a maa so pe, opuro nla ni o, ole… ati bee bee lo.
Sa o, gbogbo ariwo buruku ti awon asofin yii n pa, oro kan ti Aare Muhammed Buhari tenumo ni pe, “E je ki a se pelepele o, gbogbo agbaye lo n wo esin ti a n fi ara wa se yii, se e kuku mo pe ko ye ki won maa ba wa nidii iru nnkan bayii…”
Ohun ti Aare n so ree lati fi pa enu won mo, sugbon o jo pe won ti ni in sinu lojo naa. Bo ti se soro yii, bee lawon kan nibe patewo fun un, sugbon awon ti ko se tie yii, won ko sai foju Aare orile-ede yii ri mewaa, nitori won n ho le e gidigidi ni, bee ni won fe da nnkan ru mo om lowo paapaa lojo naa.
Eyi ni bi itakuroso ohun se lo …
Aare Buhari: A ti sa pa wa lati ri i pe a koju awon oke isoro, bee ni orile-ede yii n te siwaju ni gbogbo onakona.
Awon aosfin: Iro nla!
Aare Buhari: Eto oro aje orile-ede yii ti bo lowo ajoreyin...
Awon asofin: Rara ooooo….iro nla le pa!
Aare Buhari: Opo ise la ti se lori ise agbe, ati ohun amayederun mi-in pelu awon ohun to le mu ilosiwaju ba awujo wa…
Awon asofin: Iro buruku gbaa ni!
Bee lawon mi-in n pariwo barawo nisale, eyi to tumo si ole.
Nibe gan-an ni Buhari ti ran won leti wi pe, “Gbogbo aye ma lo n wo wa …”

Post a Comment

0 Comments