GBAJUMO

ODUN KU SI DEDE: SAURA ALAMU OLORIN FUJI TI JADE LAYE O *WON NI AISAN RANPE LO PA A



Bi odun yii se n lo sopin, ti opo eeyan n gbadura wi pe ki Olorun je ki awon ropin odun, o seni laanu wi pe, gbajumo olorin fuji ti okiki e gba igboro kan nigba kan, Alhaji Surajudeed Alamu Akere, eni tawon eeyan tun mo si Saura ti ku o. Aisan ranpe ni won lo pa a paapaa.

Lana-an ojo Aje Monde, ni won so pe okunrin onifuji naa jade laye leyin aisan ranpe to se e, bee ni won ti sin in nilana esin Musulumi.
Surajudeen Alamu Akere naa gbiyanju daadaa ta a ba n so nipa awon olorin fuji ti won je odomode ti okiki won kan daadaa laarin odun 1980 si odun 1990. Orin saje ni won fi mo on nigba yen, bee Olubadan ti ile Ibadan bayii, Oba Saliu Adetunji lo gbe e jade nigba naa labe asia ileese e, iyen Babalaje Records.
Orin saje Bebe Isila eti odo to ko nigba naa lohun-un lo fun un lokiki nla, ti awon eeyan si gbo orin e daadaa kaakiri ile Yoruba, paapaa l’Ekoo atawon ibomi-in naa.

Sa o, lojiji ni awon eeyan ko gburoo okunrin olorin fuji yii mo, ti o si pe pupo ki o too tun maa jade. Bee ninu iforowero kan to se lori redio nigba kan seyin lo salaye wi pe, lara ohun to mu oun ni idojuko lawon igba yen kan seyin ni iwa omode ti oun pelu awon akegbe oun lasiko ti irawo awon n lo soke laalaa hu, ati pe lasiko ti oun ti jade pada yii, oun yoo tun m’oke leekan.
Sugbon gbogbo igbiyanju e lati tun moke leekan si i nidii ise fuji, o seni laanu wi pe iru ariwo ati okiki to ni nigba to koko jade, kadara ko se e loore iru e mo.

Lara awon rekoodu to se nigba naa ni Shalimar, Ale ni Show, Under lo fowo si ati bee bee lo.
Ni bayii ti won ti sin Surajudeen Alamu Akere, eni tawon eeyan tun mo si Saura, gbogbo eto yooku tawon molebi, paapaa awon olorin fuji egbe e ba ni fun un la o maa fi to yin leti.

Post a Comment

0 Comments