Pitimu lero pe si Iga Oba niluu
Ijora Oloye lana-an lasiko ti Oba Fatai Aremu Aromire se idupe ayeye ojoobi
odun merindinlaadorin (66) loke eepe.
Orisirisi ohun elo ti awon
eeyan le maa fi wa ounje oojo won ni Kabiesi pin lojo naa lati fi ro araalu
lagbara.
Bee gege lawon eeyan ti won ni
ipenija-ara lorisirisi, paapaa awon ti won nilo keke gba ebun ohun lo sile.
Kabiesi ninu oro e so pe ope ni
oro ohun to si, ati pe ti oun ba mu ninu ohun ti Olorun fi ke oun fi ran awon
eeyan to ba ku die kaato fun lowo, ninu oore Olorun ni.
Lara ohun ti won pin lojo naa
ni ero amunawa iyen genereto, masinni iranso tawon telo, keke ti awon aro le
maa lo, ero ti won fi n lo ata atawon irinse mi-in lorisirisi
0 Comments