GBAJUMO

SAKA OROBO, OLORIN FUJI FE SE BEBE L’EKOO *REKOODU TUNTUN LO FE FI FOGBA YANGA


Gbogbo eto lo ti pari lori ayeye nla kan ti aare egbe awon olorin fuji tele, Alhaji Saka Ayinde, eni tawon eeyan tun mo si Orobo fe se l’Ekoo lasiko odun.
Ojobo, Tosde, ojo ketadinlogbon osu yii ni okan ninu asaaju awon olorin fuji yii so pe oun fe se ikojade rekoodu oun tuntun to pe akole e ni CHANGING OVER.
Ile igbafe kan to n je Finishing Touches Hotel & Lounge lojuna Lekki, Epe, Expressway, ni Ayo bus stop, legbee Greenland Estate, Olokonla Ajah, l’Ekoo lo so pe eto ohun yoo ti waye. Aago merin ni eto ohun yoo bere, nibi ti awon olorin nla nla naa yoo ti darapo mo on lati ba a seye ohun pelu awon sorosoro ati osere tiata pelu.
Ninu oro Saka Orobo lo ti so pe, “Bi odun yii se n pari lo, ohun kan ti o wa si mi lokan ni bi maa se fun awon ololufe mi lorin pataki ti won a fi sodun, eyi ti yoo mu inu won dun, ti won a le gbo daadaa lasiko ti won ba n se faaji odun, ti won a si tun maa gbo leyin poposinsin odun.Ohun ta a ko jo sinu rekoodu yen yato pupo, awon orin gidi ni ti omode le gbo, ti agbalagba naa le gbo daadaa, bee la tun lo rekoodu tuntun yii lati fi salaye awon nnkankan to se koko fawon eeyan lati mo, ti a ba n so nipa orin.”
Orobo fi kun un wi pe, “Mo ti n se rekoodu, eyi ta a se yii yato, nitori o fi ajulo nla ti orin fuji ni lori awon orin yooku han daadaa. Ti a ba n so nipa orin ni Nigeria, iwaju ni orin fuji wa, idi niyen ti ko fi si orin to le so pe bawo ni orin fuji se je.”

Saka Orobo ti wa ke si gbogbo awon ololufe orin fuji lapapo lati wa si ile itura Finishing Touches Hotel & Lounge lasiko odun, lati wa jegbadun alailegbe, bee lo ti fi da awon eeyan loju wi pe eto aabo to peye yoo wa, ti awon eeyan yoo si gbadun ara won daadaa. Bee gege lo so pe, gbajumo sorosoro ori redio ati telifisan nni, Yomi Mate eni tawon eeyan tun mo si Ifankaleluya ati Tayo Amokade, iyen Ijebu, osere tiata ni yoo dari eto lojo naa, nibi ti awon olorin ololokan-jokan atawon osere tiata naa yoo ti pe, ti ese won yoo pele paapaa.


Post a Comment

0 Comments