GBAJUMO

SHEHU SHAGARI, AARE ORILE-EDE YII TELE TI KU O

Aare orile-ede yii tele, Alhaji Shehu Shagari ti ku o. Loni in yii gan an ni won so pe o jade laye leni odun metalelaadorun-un (93).
Okunrin oloogbe omo Hausa yii ni Aare akoko nipo ijoba alagbada, to fara pe ti ile Amerika, iyen Presidential system, eyi to bere lori-ede yii lodun 1979. Se Parliamentary la n lo tele, ki awon Soja to da nnkan ru mo awon oloselu lowo lodun 1966.
Odun 1979 lo bere saa e akoko, egbe oselu NPN gan-an lo gbe e wole. leyin odun merin lo tun jade leekan si i lodun 1983. lara awon to ba a fa a daadaa ninu eto idibo ohun ni Oloogbe Obafemi Awolowo, omo egbe oselu UPN loun n se ni tie, sugbon Shagari gan an lo tun wole leekan si i.
Saa keji to sese bere e lo n ba a lo lodun 1983, leyin osu meta to bere saa e keji ohun lawon ologun fipa gbajoba lowo e, ti won si fi Ogagun Muhammed Buhari se olori orile ede yii nigba naa.
Orisirisi awon oloselu ni won ti n kowe ibanikedun si awon ebi oloogbe ohun, ohun ti won si n so ni pe, ki Olorun dele fun Alhaji Shehu Shagari to dari orile-ede yii fun odun merin ati osu meta.

Post a Comment

0 Comments