GBAJUMO

SINIMA OKUNKUN DAGBELEWO LORI YORUBAPLUS LORI YOUTUBE *SHE BABY LO SE E


Bi poposinsin odun se wa nita bayii, gbaajumo osere tiata nni, Seyi Ariyo, eni tawon eeyan tun mo si She Baby ti gbe sinima e tuntun, Okunkun sori telifisan ayelukara, iyen Youtube Channel ti oruko ikanni ohun n je Yorubaplus.
Ninu oro e lo ti so pe, “Oke okun lati ya sinima yen pelu awon agba osere bii Femi Adebayo, Laide Bakare; Leye Adeshile; Kenny George; emi She Baby funra mi atawon osere mi-in lolo-kan-o-jo-kan.”
She Baby te siwaju ninu oro e wi pe, ohun to mu oun gbe sinima naa sori Youtube lasiko odun yii ni lati fun awon eeyan lanfaani, paapaa lasiko ti olide wa nita yii lati le wo sinima akonilogbon yii lori Yorubaplus. Bee lo fi kun un wi pe, ona ara otun loun gba yo lori ise tuntun yii.
O ni, “Opo eeyan ni won ki i foju si awon ona mi-in ti igbeyawo le gba daru latari owo agbere sise.
O ni, “A ti ri awon okunrin ti iyawo won maa n jerii won wi pe won ki i ko obirnin, bee lawon obinrin mi-in wa ti oko won a so pe won ki i se owo agbere, sugbon to je pe obirnin egbe won gan-an ni won jo n sere tidi-bodi. Eyi atawon ohun mi-in to le da igbeyawo ru, ati ona abayo si i lawon ohun to kun inu sinima yen foofo.”
She Baby tun fi kun oro e wi pe, o se pataki ki awon eeyan maa wo ipolowo to maa n wa lori youtube, eyi ti won maa n ti bo aarin sinima. O ni, “Orisirisi ona ni eeyan le gba kekoo tabi mo nipa ohun kan. Idi niyen to fi se pataki lati maa wo gbogbo ohun ti eeyan ba ba pade ninu sinima kan fun agboye, koda to fi dori awon ipolowo, gbogbo e lo se pataki ki eeyan wo daadaa. Ere lo maa n je fun eni to wo sinima, ati awa ta a ni in, bee lawon to ni ikanni ta a ti safihan sinima wa naa a jere pelu.”

Okan lara awon olorin igbalode, iyen hip-hop ni Seyi Ariyo n se, yato si orin to n ko yii, bee lo tun je gbajugbaja osere tiata to ti gbe opolopo sinima akonilogbon jade, ti won si laami-laaka daadaa. Lara awon orin to ti se pelu awon olorin nla bii Wasiu Alabi Pasuma ni; Tell me Why; bakan naa lo se Champion pelu Oritsefemi ati orin mi-in to pe akole e ni I'm in Love.
Awon sinima ti She Baby ti se tele niwonyi; Ikoko meta; Odaju omoge; Taiwo & Kehinde; Apanimayoda; Aye alaye; Emi ilu Eko; Ofin kefa;  Sibebi; Esan ati Okunkun to wa nita bayii.
Yato si eyi, opolopo sinima ni Seyi Ariyo ti kopa ninu e pelu awon akegbe e nile yii ati loke okun.  

Post a Comment

0 Comments