Ese ko gbero ni
gbongan nla kan ti gbajumo osere tiata nni, Bukky Black ti sayeye aadota odun
niluu Germany laipe yii.
Bo tile je pe o
se die ti awon eeyan ti pade gbajumo osere yii ninu sinima gbeyin, sibe aseyori
nla ni ayeye ojoobi aadota odun to se laipe yii je fun un.
Bi awon eeyan se
ti orile-ede Nigeria lo si Germany lati lo fi ijokoo ye e si, bee lawon omo Nigeria
ti won wa lorile-ede ohun paapaa jade sibi inawo ohun lopo yanturu, ti kaluku won
si n ba osere tiata naa dupe ti Olorun fun un lanfaani lati deni aadota loke
eepe.
Nibi inawo ohun,
Alaaji Sule Adio Atawewe ni gbajumo olorin fuji to forin da awon eeyan laraya. Bee
gege ni Remi Aluko, eni tawon eeyan tun mo si Igwe onifuji naa debe, ti oun naa
si forin ye omo olojoobi si.
Lara awon
gbajumo omo Nigeria to wa nibe ni Alhaji Musiliu Akinsanya, eni tawon eeyan tun
mo si MC Oluomo, oun naa ba won debe, bee lo se bebe lojo naa, nibi to ti dun
omo oninawo ninu daadaa.
Ninu oro Bukola,
eni tawon eeyan tun mo si Bukky Black lo ti dupe lowo Olorun fun anfaani nla to
fun un. O ni, “A dupe lowo Olorun to fun mi ni anfaani lati ri ojo oni. Opo ojo
lo ti ro ti ile ti fa mu, sugbon ninu ohun gbogbo ki a maa dupe ni, paapaa fun
Olorun ati gbogbo awon eni bii eni, awon eeyan bii eeyan ti won wa ye mi si. Emi
gan-an ni olope, lojoojumo ni n o maa dupe lowo Olorun fun bo se da mi si.”
Bukky Black ti
wa fi da awon ololufe e loju wi pe, laipe ni won yoo gburoo ohun rere latodo
oun.
0 Comments