Lagbo
ariya kan lana-an Sannde ni gbajumo sorosoro kan ti a foruko bo lasiiri ti tufo
Ogbeni Joel, Ajayi eni to maa n fun fere leyin Wasiu Ayinde.
O
ni, o seni laanu wi pe okunrin naa ti ku o! Bo ti se soro yii ni agbo ohun daru,
ti awon olorin nla ti won wa nibe, ti won mo Joel daadaa bu sekun, ti opo si
fajuro wi pe iru isele buruku wo tun ree laarin awon olorin ni Nigeria.
Ni
nnkan bi ose meloo kan seyin ni okan lara awon omo eyin Oluaye Fuji, Alhaji
Wasiu Ayinde ti koko jade laye. Dipo Odebode ni won pe oruko e, lojiji lokunrin
naa ku.
Lasiko
ti isele yii waye, ni Joel to maa n lo irinse orin kan leyin Ayinde, eyi ti won
n pe ni Sax naa ti n saisan. Bo tile je pe alaafia lawon eeyan n toro fun
okunrin yii, sibe ojiji ni won gbo wi pe oun naa jade laye lana-an.
Bi
isele yii ti waye lawon eeyan ti n so o wi pe afi ki okunrin onifuji yii mura
daadaa, ki irufe isele buruku yii ma tun waye mo ninu egbe akorin e.
Won
ni ohun ibanuje ni, bi meji ninu awon omo egbe e se fo sanle ti won ku laarin
ose meloo sira won.
Ju
gbogbo e lo, ninu ibanuje lawon akegbe won wa bayii, ti awon eeyan si ti n
ranse ibanikedun si won.
0 Comments