Bi awon
omo ile igbimo asofin Eko ti se fun Gomina Akinwunmi Ambode lojo meje lati tete
dahun si orisirisi esun ti won ka si i lese ki won ma ba a le e nile-ijoba,
sugbon o, oro ohun ti ba ibomi-in yo bayii.
Egbe
ajafetoo kan ti oruko won n je Legislative Probity and Accountability (LPA) lawon
naa ti bo sita bayii, ohun kan ti won si n so ni pe, nitori Jimi Agbaje gan-an
ni won se n dunkoko mo gomina ohun, ati pe owo awon omo ile igbimo asofin ohun
paapaa ko mo, bee lawon setan lati ba won fa a daadaa lori awon owo kan to ha
sowo awon naa bayii, to si ye ki araalu mo bi won se na an.
Ninu
atejade ti alaga egbe naa, Olu Fajana fowo si lo ti soro ohun.
Egbe
ajafetoo to n ri si agbekale eto ofin sise to moyan lori, ti ko si ni bayobayo
kakan ninu ti wa fesun kan awon omo ile igbimo asofin Eko wi pe owo awon naa ko
mo, ati pe ti won ba fe tu idi Akinwunmi Ambode wo, awon naa gbodo setan lati
salaye awon owo kan to poora mo abenugan ile igbimo asofin ohun lowo iyen, Asofin
Mudashir Obasa.
Ni bayii,
won ti fun ile igbimo asofin ohun ni ojo marun-un lati salaye bi owo to fe to
bilionu mokandinlogbon, eyi to je owo-ina fun ile igbimo asofin ohun to ti bo
sowo olori ile igbimo asofin naa, Mudashiru Obasa lowo.
Bakan naa
ni won so pe awon ti setan bayii lati ko awon omo orile-ede yii sodi lati koju
oro si ile igbimo asofin ohun, ti won ba ko lati salaye bi won ti se owo goboi
yii, bee gege ni won tun so pe, lara ohun tawon yoo lo fi ba awon asofin ohun ja
ni liana ofin atawon ona mi-in to ye labe ofin orile-ede yii.
Fajana fi
kun oro e pe, “O seni laanu wi pe awon asofin yii ti kuna ninu esun awuruju ti
won fi n kan Gomina Ambode wi pe oun lo n gbe owo sile fun Jimi Agbaje to n
dije labe asia egbe oselu PDP. Bakan naa ni won tun ti kuna lori esun ti won fi
kan an wi pe oun lo wa nidii bi eto ipolongo egbe oselu APC se daru n’Ikeja l’Ekoo
nibi ti awon janduku kan ti kolu MC Oluomo, ti eeyan kan ku, tawon mi-in farapa
yannayanna, paapaa okunrin onimoto ohun, Ahaji Musiliu Akinsanya, iyen MC
Oluomo.
“Ninu
afojusun wa lati ri i pe ko si ooto kankan ninu esun ti won fi kan Gomina
Ambode wi pe o se awon owo kan basubasu paapaa lori oro eto isuna owo odun 2018
ati todun 2019. Oro oselu ko kan awa rara o, sugbon ohun ti awa n gbiyanju lati
so ni pe, ti awon omo ile igbimo asofin yii ba lawon fe ye idi gomina yii wo,
awon naa gbodo setan lati ma ni ebo kankan ninu eru won.” Fajana lo so bee.
O fi kun
oro e pe, “Ohun kan to daju ni pe owo to fe to bilionu mewaa naira (N9.6
billion) ni Mudashiru Obasa maa n gba lodoodun, ni bayii, owo to ti bo sapo oun
nikan ti fe to bilionu mokandinlogbon naira (N28.8billion), bee owo to bo sowo
awon omo igbimo asofin yooku ko ju bilionu meji-o-le (N2.4 billion) laarin odun
meta ti won ti wa nipo.
“Ibeere wa
ni pe, nibo ni owo yooku to le ni bilionu merindinlogbon (N26.4 billion) wa? O
se pataki ki ile igbimo asofin Eko o so bi owo yii se je ki won too so pe awon
yoo sewadii Gomina Ambode tabi yo o danu nipo bii eni yo jiga.
“Ati pe o
je iyalenu wi pe owo to to egberin milionu (N800 million) nile igbimo asofin
yii n gba losoosu, ninu eyi ti asofin koookan yoo ti mu milionu meji naira lo
sile losu kan.”
Te o ba
gbagbe, ile igbimo asofin Eko ti fesun kan Gomina Ambode wi pe okunrin naa na
awon owo kan lai tele ilana to ye, paapaa lori bi ko se fi to awon asofin Eko leti
ko to na an.
Bo tile je
pe ile igbimo asofin Eko ti pin si meji bayii lori oro ohun, bi awon kan se fe
ki won le e danu lori esun ohun, bee lawon mi-in n so pe ori bibe ko ni oogun
ori fifo.
Lara esun
ti won ka si i lese ni pe gomina naa na owo to to bilionu mejilelogun (N22bn)
fun akanse ise kan lori eto irinna oko lagbegbe Osodi, eyi ti won pe ni
Oshodi-Transport Interchange. Won ni gomina yii na owo ohun lai je ki ile
igbimo asofin Eko fowo si i.
Bee gege
ni won tun so pe opuro ni gomina ohun lori bo se so pe owo to to milionu
aadorin naira (N700m) loun ra boosi kookan ti yoo maa ko ero kaakiri ipinle
Eko. Won ni owo to so pe oun na yii ti poju, ati pe nise ni Gomina Akinwunmi Ambode
bu owo gegele le e.
Yato si
eyi, won tun ni ko wa salaye bo se maa so pe oun na aadota milionu naira (N50m)
lori kiko ibudoko awon boosi bii ogorun-un kaakiri igboro Eko.
Won ni
pelu gbogbo esun yii, o foju han wi pe Gomina naa ti kolu ofin orile-ede yii,
bee lo ni lati so tenu e ki awon ma ba a le e danu kuro nipo gomina laarin ose
kan pere.
Sa o, ohun
ta a gbo ni pe, yato si oro Jimi Agbaje ti won so pe gomina yii n dogbon fowo
ran lowo, won ni awon omo ile igbimo asofin yii n binu si owo kan to ye ki o je
ajemonu won ti gomina yii ko lati bu owo lu, ki won le ba a gba a. Won ni won
ko sese maa gba iru owo bee lowo awon gomina to ti je tele, sugbon bi Ambode se
yari kanle yii lo je ki awon naa maa wa orisirisi esun si i lese. Pelu
gbogbo rukerudo yii, ohun ta a gbo ni pe nise ni gomina yii n ba ise ilu lo ni
tie, ti ko wo ariwo oja rara.
Nibi ti
oro ohun yoo ja si, oju ree, iran ree.
0 Comments