Lara awon akitiyan osere onitiata yii lo so o di alakooso egbe
kan to n je #NEXTLEVEL; egbe to n sapa-saapon lori ipolongo bi Aare Buhari ati
igbakeji e, Ojogbon Yemi Osinbajo yoo se wole leekan si i. Bakan naa lo tun je
abenugan fun egbe mi-in tawon naa n sakitiyan bi Buhari/Osibanjo yoo se wole
pada, iyen Director of Contacts & Mobilization nipinle Eko.
Ninu oro e lo ti so pe, “Gege bi osere ati atokun eto lori
telifisan, o pe ti mo ti je okan lara awon omo egbe to n ja fetoo awon araalu
lorile-ede yii, sugbon irufe isejoba rere ti Buhari/Osinbajo n se lorile-ede
yii lo so emi deni to n da soro oselu bayii. Isejoba won gbayi pupo, ayipada
nla ti won ti mu ba orile-ede yii gan-an lo je ki emi naa nifee lati sepolongo
fun won, ki won le pada leekan si i.
Bose Olubo fi kun oro e pe, bo tile je pe oun ko ni ajosepo
kankan pelu yala Aare Muhammed Buhari tabi Ojogbon Yemi Osinbajo, sibe awon ise
amayederun ati bi won se n gbogun ti iwa ibaje ti to fun gbogbo eeyan to ba n
wa ilosiwaju Nigeria lati wa gbogbo ona rere labe ofin ki won le te siwaju ninu
ise idagbasoke won.
![]() |
| Otunba Bisi Kolawole |
“Awon ise akanse ti ijoba yii ti se laseyori ko lonka,
paapaa ti a ba n so nipa odun keresimesi ta a se lo yii ti ko si wahala
owongogo epo petiroolu rara titi digba ta a sodun tuntun yii. Eleyii gan-an to
lati fi ijoba yii han gege bi eyi to mo ibi ti bata ti n ta araalu lese, to si
setan lati fopin si gbogbo ohun to ba n je won niya pata.”
Bose Olubo ti so pe ko ni i salai ya opo eeyan enu, nitori pe
pupo ninu araalu ni won fe ki ijoba yii te siwaju.
Siwaju si i, gbajumo osere yii ti so pe bo tile je pe Aare
Buhari, eni ti se omo egbe oselu APC loun n polongo ibo fun, lori bi yoo se tun
se aare leekan si i, sibe awon gbajumo oloselu meji kan wa niluu abinibi oun,
Otunba Bisi Kolawole ati Otunba Lekan Akindele, tawon naa n sise idagbasoke
alailegbe lekun idibo won.
O ni, bi a ba se n sise fun bi Aare Buhari ati igbakeji e yoo se
pada, awon eeyan mi naa ti setan lati fi ibo won da awon mejeeji naa pada, ki
ise ilosiwaju ti won gun le ni Efon Alaaye le tubo te siwaju daadaa.
O fi kun oro e wi pe, pupo ninu awon ti ko mo oun daadaa ni won
n lero wi pe boya oun sese darapo mo oselu ni. O ni, “Asiko kan tie wa ti alaga
ijoba ibile kan n foju oloselu kekere wo mi, bee ojo ti n pa igun mi bo ojo pe
nidii oselu. Mo ranti daadaa wi pe lati aye ijoba ibile Kosofe ojohun lemi naa
ti wa ninu oselu, ti mo si n kopa ribiribi, koda lati odun1993 ni paapaa. Bakan
naa ni mo tun je ojulowo oloselu bayii nijoba ibile Ila-oorun Eti Osa, iyen Eti
Osa-East, emi gan-an ni mo maa n ba won sasaro lori oro to ba je mo eto iroyin.
“Okan lara awon to n ja fetoo araalu ni mi, bee ni mo mo nipa
okoowo daadaa ati ise sinima, bee ni mo tun je olorin, bakan naa ni mo tun je
akosemose nipa ka se eto kara-o-le, iyen body fitness fun awon eeyan.
“Yato si awon ise ti won mo mi mo yii, ki ara tu araalu je ohun
to je mi logun pupo, ati pe asiko ta a wa yii, ki i se igba ta a gbodo maa so
pe awon eeyan kan ni ojulowo oloselu, ti awa yooku a wa kawo gbera maa wo won
niran, ti won a maa se ilu bo se wu won. Ko siyen mo bayii, a o jo se e ni, ki
ilosiwaju gidi le ba awujo wa. Erongba mi ni bi ilosiwaju yoo se de ba
orile-ede yii, ti ilu mi, Efon Alaaye naa yoo da bii ilu oyinbo
kekere.
Okan lara awon osere tiata Yoruba to loruko daadaa nidii ise
ohun ni Bose Olubo n se, bakan naa lo je akorin, to si tun maa n se atokun eto
lori telifisan ni Nigeria nibi ati loke okun. Oun naa lo ni eto kan ti won n pe
ni Bose Olubo show.
Nibere odun 90s gan-an lo bere ise amuludun, ninu eyi to ti se
rekoodu orin marun-un, to si tun ni awon sinima agbelewo metadinlogbon (27).
Oun gan-an lo nileesee Amazon B Communications, ileese ti won ti maa n ba ni
seto igbohun-safefe, ise sinima, atawon ohun meremere mi-in. Yato si eyi, oun
gan an naa ni oga agba fun ileese Amazon Nature, ileese to maa n po ipara
igbalode atawon ohun mi-in tawon obinrin fi maa n se oso ara ati
a-mu-ara-jolo.
Ileewe giga Yaba College of Technology, l’Ekoo ni Bose Olubo ti
kawe gboye imo Komputa. Oun naa lo maa n kopa IYA ALATE, iya arugbo eni odun
marundinlaadorun-un (85) ninu ere onise ori redio ati telifisan. Bakan naa lo
tun je asoju-koroyin fun ileese BEN TV to wa ni New York lorile-ede Amerika.
Orile-ede yii ni gbajumo osere yii n gbe, bee lo tun n gbe ni New Jersey niluu
Amerika.
Ni Nigeria nibi, titi to fi de oke okun ni won mo Bose Olubo
gege bi ololufe Buharim ti ipadabo e je logun, to si n kede ihinrere nipa
Buhari\Osibanjo fun ibo 2019.





0 Comments