GBAJUMO

OHUN TO MU WA YATO SAWON YOOKU TO N KO AWON EEYAN LO FUN HAJJ- BIN SHITTU

 Bi awon Muslumi se n gbaradi lati darapo mo awon elegbe won kaakiri agbaye lorile-ede Saudi Arabia fun ise hajj odun yii, ileese BIN SHITTU Travels and Tours loun ti bere iforukosile  fun awon Alalaaji bayii.
Ninu atejade kan ti oga ileese ohun, Alhaj Shittu Olasunkanmi Ismaheel,  eni tawon eeyan tun mo si Bin Shittu fi sowo si wa lo ti fidi e mule wi pe, ise ti n lo lori bi awon Musulumi ti won fe ba ileese ohun lo si ile Mecca lodun yii yoo se sise ohun lasepe.
O ni, “Ileese nla kan nileese Bin Shittu Travels and Tours ta a ba n so nipa ki a ko awon eeyan lo si ile mimo fun ise hajj, awa ko ni i fara pamo je enikeni niya, nitori iberu Olorun la wa fi n se ohun gbogbo ti a ba dawole. Ise hajj odun 1440 A.H yii, iyen hajj odun 2019, iforukosile ti bere lodo wa, bee lawon eto to maa je ki gbogbo ise Alalaaji lo niroroun pata la ti n sare e bayii. Se irorun awon alabaara wa lo je wa logun, ohun lo si se pataki si wa pupo.
“Mecca todun yii, orisirisi eto la ti gbe kale fun irorun awon to fe ba wa rin irin-ajo ohun. Owo milionu kan abo naira (N1.5M) ni arinrin-ajo maa san. Ise asepe, ile ti won maa de si, ti ko jinna si Kaaba, moto ta a maa gbe won lo gbe won bo, bee lawon Onimo ti wa pelu ti won yoo je oluranlowo fun won lati mu ise won ya, ti won yoo si se ise won lasepe. Ojo ti a ba so pe a maa gbera naa la maa lo, bee lojo ti a ba so pe a maa de pada si Nigeria ko ni i ye, eto itoju ati amojuto ilera awon to fe ba wa rin irin-ajo naa se pataki pupo si wa, bee lawon eeyan yoo si dupe, nitori ijosin alasepe ni won yoo se pelu ileese Bin Shittu to fe ko won lo.
“Awon ti won ti ba wa rin irin-ajo yii daadaa mo wi pe, ileese to se fokan tan ni wa, bee la kunju osunwon daadaa ta a ba n so nipa ki a ba eeyan seto irin-ajo si oke okun kaakiri agbaye.”
Awon nomba te e le pe awon alase ileese Bin-Shittu si ree fun ekunrere alaye: 08065823401 tabi 08024414786. Bakan naa le tun le lo sori alatagba yii www.binshittu@yahoo.com.

Post a Comment

0 Comments