Pitimu loju pe, ti ese pele si gbongan
nla 10 DEGRESS ni Billing ways, Oregun l’Ekoo loni-in Satide, ojo Abameta, iyen
ojo kejila, osu kin-in-ni odun yii nigba ti Aare Ona Kakanfo fi awon omo Yoruba
ti won laami-laka joye lorisirisi.
Ninu oro Iba lo ti so lajori
ohun to fa a ti eto oye pataki ohun fi waye. O ni
“Gege bi Aare Ona Kakanfo ile Yoruba,
mo ri i wi pe o se pataki ki a ni awon asoju kaakiri ile Yoruba ti won yoo
dabii alagbawi fun Iba. Ko rorun ki Aare Ona Kakanfo to n gbe l’Ekoo mo ohun to
n sele ni Kwara, Ondo, Oyo, Ekiti, Osun; Kogi atawon ile Yoruba yooku leekan
naa, nitori e gan-an la se ni awon asoju. Awon ti a fun loye loni-in yii je
ojulowo omo Yoruba, ti a o jo maa jokoo ajoro lori bi ile Yoruba yoo se ni
ilosiwaju pelu ajosepo pelu awon oba alaye, ti iya kankan ko ni i je omo
kaaro-o-jiire, ti awon eeyan wa ko ni i di atemere laelae.”
Aare ona Kakanfo tun te siwaju
ninu oro pe, eto isejoba Aare Ona Kakanfo asiko yii yoo yato si ohun tawon
eeyan ti mo tele, ati pe ijoba toun yoo maa samulo awon omo igbimo lati gbogbo
ipinle kookan nile Yoruba ki ilosiwaju gidi le wa fun t’olori-telemu, ti iya kankan
ko ni i le je omo Yoruba.
O ni, o se pataki ki a ni awon
asoju ti ko ni i je ki eti wa di si awon ohun to ba n lo lagbegbe won, Aare ko
le maa gbe l’Ekoo mo ohun to n sele ni Shaare nipinle Kwara lohun-un tabi ni
Kabba lodo awon Okun. Ti wahala ba sele nibi kan, tabi ti agbegbe kan niloo
akiyesi Iba, awon asoju yii ni won maa jiroro pelu Iba ati oba alaye ilu tabi
agbegbe
naa, ti atunse yoo si waye lori ohun to ba je edun okan tabi idaamu to
ba n ba iru agbegbe bee.
Iba Gani Adams tun fi kun oro e
pe, lose kan, ibi apeje atawon ijokoo lorisirisi ti won maa n pe Aare si maa n
le ni ogoji. O ni, fun idi eyi, o se patakim ki Aare Ona Kakanfo ni awon asoju
ti yoo maa lo soju fun un nibe. Lara awon ti Iba fun loye lojo naa ni Alhaji Yakub Babatunde Adeshina, eni to nileewe olukoni, Adeshina College of Education to wa niluu Shaare nipinle Kwara, bee lo fun awon eeyan pataki mi-in loye lojo naa
*EKUNRERE ALAYE TI IBA GANI
ADAMS SE LORI OHUN TO MU UN YAN AWON OLOYE TUNTUN YII ATI IGBIMO ELENI-AADORIN TI
YOO MAA BA A SASARO LE O BA PADE LORI TELIFISAN WA…. E tete kan si ikanni yii…De.reportorial
TV lori Youtube nibe le o ti wo o bi gbogbo eto ohun se lo…e ku oju lona oooo
0 Comments