GBAJUMO

IBO KU SI DEDE: AWON OMO EGBE OSELU APC NI LONDON BEBE FUN ALAAFIA LAARIN ILU

Bo ti se ku dede ki eto idibo waye nipinle Oyo, awon omo egbe oselu APC, ti won je omo ipinle ohun ti won n gbe niluu London ti ke si ajo eleto idibo atawon mi-in ti oro kan lorile-ede yii lati ri i daju wi pe eto idibo ohun lo woorowo laisi wahala kankan.
Ni bayii ti eto idibo ti ku ojo mejidinlogoji (38 days), eyi gan-an lo mu awon araalu oyinbo yii so o ninu atejade kan ti won fowo si leyin ipade ti won se ni London lojo Ojoru, iyen Wesde to koja.
Lajori ohun ti won si so lojo naa ni bi gbogbo awon alenu-loro ti oro idibo ohan kan kaakiri orile-ede yii yoo se gba alaafia laaye ti ko fi ni i si ruke-rudo kankan saaaju ki idibo ohun too waye ati lasiko to ba n lo lowo ati leyin ti won ba pari e tan.
Saaju si i, ninu atejade ohun ni won ti ro gbogbo awon eeyan ipinle Oyo ti won ye leni to le dibo lati lo gba kaadi idibo-ala-lope won, ki awon naa le lanfaani lati dibo yan eni rere ti yoo tuko ipinle Oyo.
Ninu oro alaga egbe oselu APC niluu London, Ogbeni Kolawole Saidu, nigba to n soro loruko gbogbo omo egbe lo ti fidi e mule wi pe wamuwamu lawon duro leyin oludije egbe oselu APC, Ogbeni Adebayo Adelabu to n dije fun ipo gomina nipinle Oyo lori bi yoo se jawe olubori ninu osu keta odun yii.
Siwaju si i, awon omo egbe oselu yii ti fidi e mule wi pe awon setan lati sise papo pelu alaga egbe naa nipinle Oyo, Baba Oke ati akowe egbe ohun, Alhaaji Mojeed Olaoya lati ri i daju pe, Oloye Adebayo Adelabu jawe olubori ninu ibo gbogbo-gboo ti yoo waye laipe yii
Lakootan, awon omo egbe yii ti ke si awon eso eleto aabo lorile-ede yii lati sise won bii ise ki eto idibo naa le lo woorowo kaakiri orile-ede Nigeria.

Post a Comment

0 Comments