Lati mu eto oro aje gbooro daadaa nipinle
Eko, oludije fun ipo gomina labe asia egbe oselu PDP, Ogbeni Jimi Agbaje ti so
pe ijoba oun yoo faaye sile fun awon ileese aladaani lati sise po pelu ijoba,
ti oun ba wole sipo gomina.
Agbaje fi kun oro e wi pe, ijoba oun yoo faaye sile fun eto oro
aje ti ko ni i fara ni awon onileese aladaani lara, ti aaye yoo wa fun won daadaa
lati mu eto oro aje ipinle Eko gbooro daadaa.
Bakan naa lo so pe, awon odo
naa yoo ri tiwon se ninu ijoba oun, paapaa lori eto ibasepo ti ijoba oun fe
gunle pelu awon onileese adani lorisirisi.
Oludije fun ipo
gomina labe asia egbe oselu PDP tun so pe, gbogbo eeyan ti won ba ti ni ohun
rere ti won fe se fun ipinle Eko atawon eeyan e, paapaa nipa eto oro aje nijoba
oun yoo faaye gba.
“Ohun akoko to le je isoro fun awon onileese adani, ni bi won yoo
ti sowo pelu ifokanbale, ajosepo ti yoo fun won ni ifokanbale lawa setan lati fun
won. Eleyii ko ni i salai mu ilosiwaju nla ba ipinle Eko, nitori, yoo fun ipinle
wa lanfaani lati kuro ni ipo ketadinlogun to wa lo si ipo kin-in-ni ninu eto oro
aje.”
Jimi Agbaje te siwaju ninu oro wi pe, “Bee gege ni eleyii yoo fi
awon eeyan lokan bale wi pe ni kete ti o ba ti de Eko, kiakia ni okoowo re yoo
maa se daaadaa latari ajosepo ti ijoba ipinle Eko
yoo ni pelu awon onileese adani, ati pe irufe ajosepo yii yoo so
eso rere lorisiri ona.
“Ohun ti awa fe se ni pe, a ko ni i fe ki ileese aladaani maa ri
ijoba gege bi olopaa to fe gba gbogbo ohun ti won ni lowo, tabi
a-gba-lowo-meeri; dipo bee, ijoba wa yoo sise papo pelu won ni, bakan naa ni yoo
fun awon odo lanfaani lati kose-mose labe irufe ileese aladaani bee.
“Sugbon ta a ba ri ibi ti eru ba ti n ba awon onileese aladaani,
wi pe ohun kan t’ijoba mo ko ju bi won yoo se gba gbogbo ohun ti won ba ni, ajosepo
to dan moran ko ni i le waye, bee ni ko ni i le mu ilosiwaju gidi kan ba awon odo
ti won n bo n leyin, Ko si ye ko ri bee rara.”
Lakootan, Agbaje ti so pe, “Labe akoso mi gege bi gomina ipinle
Eko, anfaani yoo wa lati mu eto oro aje gbooro daadaa. Labe isakoso mi gege bi
gomina, emi gan-an ni yoo maa dari eto, ti maa si maa lo ipo mi gege bi alase, emi
ko ni i maa lo gbase lodo enikeni.”
WO FIDIO JIMI AGBAJE LORI IKANNI YII:
0 Comments