![]() |
Adebola, omo Karube Original to fe seyawo |
Satide ojo Abameta ose yii ni gbajumo olorin fuji nni,
Alhaji Adebisi Ayinde, eni tawon eeyan tun mo si Karube Original yoo seto igbeyawo
alarinrin fun omo e, Amofin Adebola Ayinde.
Ninu atejade ti okunrin onifuji yii fi sowo si wa lo ti so
pe, aago mewaa aaro ni eto ohun yoo bere nile e, to wa ni nomba 4, Opeyemi
Close, Idole, Ileshi ni Gas line bus stop agbegbe Sango nipinle Ogun. Nibe
gan-an ni eto mo-mi-n-mo-o, eyi tawon eeyan tun mo si Introduction yoo waye.
![]() |
Karube Original, iyawo e ati omo won looya ree |
Karube Original ninu oro e ti dupe lowo Olorun lori omo
oloriire ti Olorun fun un. O ni, “Mo dupe wi pe a bi omo naa saye, Olorun tun
ni ko ju awa lo ninu imo, onifuji ni mi, orin fuji ni mo n ko, sibe Olorun fun
emi naa lanfaani lati to omo titi, to fi di agbejoro niwaju adajo. Iyen nikan
ko o, mo tun fe fa a fun oko lose yii, ope ni oro mi, ki Olorun fi adun sinu
igbeyawo won, ki o si je ki gbogbo alabiyamo pata o jere omo.”
Gbogbo eto lo ti pari bayii lori igbeyawo alarinrin naa, bee
lawon akegbe e nidii ise fuji ti so pe, awon yoo debe lo ba a seye nla fun omo
e to fe sin rele oko.
0 Comments