Ninu
ibanuje nla lawon osere tiata Yoruba wa bayii lori iku ojiji to pa okan pataki ninu
won.
Gbenga
Akintunde, eni tawon eeyan tun mo si `Burger’ lo ku lojiji, aisan iba gan-an ni
won so pe o pa a.
Gbajumo
osere tiata nni, Kunle Afod gan-an lo kede iku e lori ero ayara-bii-asa e, Instagram,
to pe ni @kunleafod.
Omo
Oyo ni won pe Gbenga Akintunde, eni odun marundinlaadota (45) si ni, bee oun
gan-an ni won pe ni akobi awon obi e. Ana, Tosde Ojobo ni won so pe okunrin osere
tiata yii so pe o re oun, to si gba osibitu lo, aisan iba lo so pe o n se oun,
sugbon o se ni laanu wi pe aisan naa lo pa a ki oloju too se e.
Ninu
oro Kunle Afod lo ti so pe, ‘Lana-an gan-an lo pe mi, to beere lowo mi pe se mo
si maa se ayeye ti mo maa n se nibere odun, iyen loni-in Fraide ojo kerin odun
tuntun, sugbon o se ni laanu wi pe ofo re ni won tu fun mi loni-in yii …BURGER..
“Ohun ti mo gbo ni pe funra e lo lo si osibitu
fun ayewo wi pe iba n se e, nigba ti yoo si fi to bii wakati meloo kan, nise lo
ti doku ti won gbe sinu mosuari …ibanuje nla ni eleyii fun wa.
“Bee
gbogbo wa la ti bere eto lori bi a o se seye nla fun o laipe yii, e wa wo iru ibanuje
nla ti a ko lodun tuntun.. sugbon o ye Olorun,’’
0 Comments