GBAJUMO

AARE BUHARI SO PE: TOOGI TO BA JA APOTI IBO GBA N FIKU SERE

Nibi ipade egbe oselu APC to waye loni-in ni Aare Muhammed Buhari ti kede e wi pe, janduku towo ba te to ja apoti ibo gba, yoo fi emi ara e wewu.
Aare orile-ede yii soro ohun lasiko ti egbe oselu APC sepade pajawiri kan niluu Abuja. O ti wa ke si awon eso alaabo lati mu lele, ki won si ri i pe enikeni tabi janduku to ba gbiyanju lati da ibo ru, tabi ji apoti ibo gbe, ki won mu iru eni bee, ko si fina woju ijiya to to labe ofin.
Siwaju si i, Aare Buhari ti bu enu ate lu bi ajo INEC se sun idibo siwaju, bee lo seleri wi pe ijoba oun setan lati sewadii ohun to fa a, ti ijiya to ye yoo si wa fun enikeni ti aje e ba si mo lori.
Nibi ipade ohun naa ni alaga egbe naa, Ogbeni Adams Oshiomhole ti so pea won setan lati te siwaju pelu ipolongo ibo titi di asale Ojobo ose yii. O ni, to ba je pe ile-ejo ni ajo INEC fe gba lo, awon setan. Bee gege lo tun fesun kan ajo eleto idibo wi pe nise ni won n ledi apo po mo egbe oselu PDP, ati pe gbogbo enu loun le fi so o wi pe awon omo egbe naa ti mo tele wi pe ajo INEC yoo sun ibo ohun siwaju.
Bi oro ohun ti se bale ni egbe oselu PDP naa ti so pe ko si ooto kankan ninu esun ti Adams Oshiomhole fi kan awon.
 Bakan naa ni won ti so pe, o ye ki ayewo finnifinni waye lori awon iwe idibo atawon elo idibo mi-in ti ajo naa gba pada bayii, saaju ibo ti yoo waye lojo Satide, Abameta to n bo yii.

Egbe PDP ti so pe lola gan-an lawon naa yoo sepade niluu Abuja.

Post a Comment

0 Comments