Bo tile je Aare Muhammed Buhari
ti so pe enikeni to ba ja apoti idibo gba ninu ibo ti yoo waye lojo Satide, ojo
Abameta yii see se ko fi iku se ifa je, sibe ajo eleto idibo, INEC ti so pe
awon ko fara mo igbese ohun.
Nibi ipade pelu awon oniroyin
ti ajo naa pe ni, alaga INEC, Ojogbon Yakub Mahmud ti so pe, dipo iku ojiji ti
Buhari so pe o see se ko to si enikeni to ba ji apoti idibo gbe, o ni ajo naa
setan lati tele ohun ti ofin eto idibo orile-ede yii so.
Yakub ti so pe, ohun ti awon
fara mo ni tawon ni ki eni ti owo ba te lo sewon odun meji tabi ko san owo
itanran idaji milionu naira (N500,000) gege bi ofin se la a kale, dipo iku
ojiji ti won ni ki awon eso agbofinro maa fi pa won.
O ni, “Gbogbo enikeni ti owo ba
te ti won rufin lasiko idibo, ijiya to to si si won gege bi ofin eto idibo se
la a sile lawa setan lati tele, awa ko faramo ipakupa ti Aare ni ki won pa eni
to ba ja apoti ibo gba.
Te o ba gbagbe, nibi ipade ti
egbe oselu APC pe awon alenu-loro ninu egbe ohun si niluu Abuja ni Aare
Muhammed Buhari ti kede oro ohun.
Ohun to si so ni pe, “Ti a ba
ri enikeni ti o n pe ara e ni alagbara laduugbo e, to lero wi pe nise loun yoo
da ibo ru tabi ji apoti ibo, iku ojiji niru eni bee fi n sere, nitori ko ni i
lanfaani lati seru e mo.”
Bo ti se soro yii lawon omo
egbe oselu PDP ti tako o, ti won si so pe oro ti baba naa so ku die kaato gege
bii olori orile-ede.
Ninu oro ti alaga egbe oselu
PDP, Omooba Uche Secondus so lo ti so pe oro ti Buhari so yii, nise lo fe fi
seru ba awon oludibo atawon ti won je asoju egbe ti yoo duro gbagba lati ma je
ki won yan enikeni je lasiko ibo ohun.
Nibi ipade ti egbe oselu PDP pe
lana-an Tusde ojo Isegun lo soro ohun. O ni ti a ba ri agbofinro kan to ba
yinbon pa enikeni lasiko ibo, iru agbofinro bee yoo da ara e lebi gidi, nitori
ofin orile-ede yii ko faaye gba ki won pa eeyan nipa-kupa.
Sa o, awon omo egbe oselu APC
naa ti soro, won ti so pe, idi ti awon omo egbe oselu PDP fi gbe oro naa sori ni
pe, o jo pe won ti ni in lokan lati maa ji apoti ibo kiri lasiko idibo ohun ni.
Won ni ti won ko ba ni iru ero
bee lokan, won ko ni i so oro ti Aare so yii di ohun nla ti won yoo maa gba bii
eni gba igba oti.
Ninu
oro Ogbeni Garba Shehu, eni ti se amugbalegbee fun Aare Buhari lo ti so pe,
ohun ti Aare so yii ni yoo fopin si a n ji apoti idibo gbe, nitori kaluku ni
yoo towo omo e b’oso.
Bakan
naa lo fi kun un pe, awon agbofinro ko le maa wo awon janduku niran ki won maa
se emi awon eeyan lofo latari wi pe won fe da eto idibo ru.
O
tun fi kun un wi pe, niwon igba ti iru ikilo yii ti waye latenu Aare, ko ni i
seni ti yoo fe dan iru e lasa, ati pe eto idibo to yanranti ti ko ni wahala kankan
ninu lo je Aare Muhammed Buhari logun.
0 Comments