Kaakiri odo awon fendo, iyen awon to maa n ta iwe iroyin
lawon omo Yoruba yoo ti lanfaani lati maa ra iwe iroyin Yoruba tuntun, ti oruko
re n je ASEJERE.
Ojulowo iwe iroyin Yoruba yii
ni yoo je akoko to da lori okoowo, oro aje, iroyin nipa awon osere ti won
laami-laka nidii ise sinima, orin, ti won tun je ojulowo onisowo. Bee lawon
gbajumo nla nla nidii okoowo paapaa yoo lanfaani lati gbe oro awon jade, bi won
se bere, nibi ti won ba a de, ati ohun ti eeyan
gbodo maa se, tabi yago fun, ti eeyan ba fe se asejere ninu idawole eni.
Yato si eyi, won ti so pe t’olori
telemu ni iwe iroyin ohun wa fun, ati pe ilosiwaju nla ni yoo mu ba ile Yoruba
paapaa lori igbelaruge oro aje atawon ise abinibi ile omo Oduduwa ti ko gbodo
dawati lawujo wa.
Osoosu lawon alase ileese iwe
iroyin yii so pe yoo maa jade lati asiko yii lo.
Idi kin-in-ni, eyo kin-in-ni
iwe iroyin ohun si ti wa nita bayii.
0 Comments