GBAJUMO

EYI NI BI WOLII TB JOSHUA SE SO ASOTELE WI PE IBO KO NI I WAYE LONI-IN


Iyalenu loro ohun si n je fawon eeyan nigba ti won gbo wi pe asotele Wolii TB Joshua ni nnkan bi ojo meloo kan seyin wi pe eto idibo ko ni i waye loni-in Satide ojo kerindinlogun osu yii gege bi Olorun se fi han oun.
Ni nnkan bi ojo meloo kan seyin ni  gbajugbaja Wolii agbaye nni, TB Joshua so wi pe, ti ajo INEC ko ba mura daadaa, o see se ki eto idibo ma waye loni-in gege bi ajo ohun se la a kale.
Lasiko ti Wolii ijo Synagogue of All Nations, eyi to wa ni Ikotun l’Ekoo n se waasu fun awon omo ijo e lo fi won lokan bale wi pe wahala kan bayii ko ni i sele lori idibo ni Nigeria, sugbon bi Olorun se fi han oun, ibo ko ni i waye lojo ti ajo INEC kede e, ati pe ohun ti yoo fa a ko ni i se leyin awon kudiekudie kookan to maa waye.
Ninu oro e lojo naa lo ti so pe “Ibo ta a fe di ni Nigeria lojo kerindinlogun yen, o see se ki o ma waye latari awon kudie-kudie kookan to maa waye, sugbon mo nigbagbo wi pe agbara Olorun yoo ka a.”
Bo se soro ohun niyen o, nigba to si ku dede loooto ki eto ibo waye loni-in, nni ajo naa atawon ti oro kan ba wole ijiroro lati owo irole ana Fraide ojo keedogun, nigba ti won yoo si pari ipade, nibe gan-an ni won ti so pe ibo ko ni i le waye mo loni-in o di Satide to n bo, nitori awon gbodo mura sile fun un daadaa, ki ibo naa le kesejari.
Sa o, Ogbeni Yakubu Muhammed, eni ti se olori ajo naa ti so pe orinkinniwin alaye lori ohun to mu awon taari ibo ohun siwaju lawon yoo pe ipade awon oniroyin le lori ni deede aago meji osan oni.


Post a Comment

0 Comments