Oludije fun ipo gomina
labe asia egbe oselu PDP l’Ekoo, Ogbeni Jimi Agbaje ti so pe oun setan lati gbe
eto eko laruge, nipa siso o di ise tawon eeyan yoo feran, ti won yoo si maa gba
owo to joju nidii e.
O ni, bi awon ti won
sese fe gbase oluko yoo se feran lati di tisa awon omoleewe, bee lawon ti won ti
wa lenu ise tele paapaa yoo ni ilosiwaju gidi lenu ise ohun, nipase bi ijoba
oun yoo ti se gbarukuti eto eko nipinle Eko.
Ninu fidio kan to ti
de apewo bayii ni Jimi Agbaje ti so oro ohun. O ni, o je ohun to ba ni lokan je bayii
bi ise olukoni se di ohun tawon eeyan n ya sidii e nigba ti won ba ti wase-wase
ti won ko rise.
Agbaje
so pe, “Olukoni ni iya mi, bee ni mo mo owo ati iberu nla ti awon omode maa n ni
fawon oluko laye igba yen. Ijoba
tiwa yoo da ogo yii pada, bee lawon osise yooku naa yoo ni igbe aye to tun
rorun ju bayii lo, nitori ko ni i seni ta a maa sise erin-je-ije-eliri laarin
awon osise mo nipinle Eko ta a ba ti dori ipo.
“Ijoba
wa maa so ise tisa dohun tawon eeyan yoo nifee si, ti awon odo paapaa yoo maa
sare tete lati di oluko l’Ekoo.”
Siwaju si i, o ni, “Ko si bi a se fe
karamaasiki ise awon olukoni tawon osise yooku naa ko ni i salai gbadun ijoba
wa, gbogbo osise Eko pata ni igbe aye won yoo yato ni kete ta a ba ti depo
ijoba. Eyi ni ileri wa, bee la o mu se, ti ara yoo de teru-tomo.”
0 Comments