Idunnu nla lo subu layo loni-in
kaakiri awon agbegbe kan nipinle Kwara, paapaa laarin awon omo egbe oselu APC nigba ti won kede wi pe, Dokita Bukola
Saraki ti fidi remi, ati pe ko tun nii le ba won pada sile igbimo asofin agba
ni kete ti saa to n lo lowo yii ba ti pari.
Bi awon omo egbe oselu APC se n jo,
bee ni won n yo ti won n pariwo O TO GE kaakiri ilu Ilorin.
Omo egbe oselu All Progressives
Congress (APC), Dokita Yahaya Oloriegbe lo fidi Dokita Bukola Saraki janle ninu
eto idibo to waye lana-an lati soju aarin gbungbun ipinle Kwara, (Kwara Central)
Ibo to fe to egberun lona aadorin (68,994)
ni Dokita Bukola Saraki ni, nigba ti Oloriegbe
ti won jo fa a ni ibo to le ni egberun lona ogofa (123,828) ni tie.
Loni-in yii gan-an ni asoju ajo
eleto idibo, Ojogbon Olawole Obiyemi kede wi pe Oloriegbe leni to jawe olubori.
Ni
kete ti won ti kede wi pe omo Baba Oloye ko lo wole yii ni ariwo nla ti so
kaakiri ilu Ilorin, paapaa laarin awon omo egbe oselu APC, ti won n yo, ti won
n jo, ariwo ti won si n pa kiri ni pe, O TO GE.
0 Comments