Gbogbo eto lo ti pari bayii lori ayeye MEGATO DAY to maa
waye niluu Abeokuta lojo kokanlegbon osu keta odun yii.
Lojo Sannde to gbeyin osu keta ni won so pe ayeye ohun yoo
waye, nibi ti ilu Abeokuta nipinle Ogun yoo ti gbalejo Alhaji Wasiu Alabi
Pasuma, ti awon alafe eeyan yoo si lanfaani lati jegbadun ara won, ti won yoo
tun gba ebun repete lo sile.
Ninu atejade ti awon alase ileese MEGATO, iyen egboogi to n
mi gboro titi bayii latari orisirisi ise alaranbara to n se lago ara fi sita ni
won ti so pe, MEGATO CARNIVAL ohun maa larinrirn, eyi ti yoo bere lati aago
mewaa aaro ni DAKTAD HOTEL QUARRY ROAD, niluu ABEAOKUTA.
Okan lara awon abenugan ileese ohun to ba wa soro saleye pe,
“Ofe ni o, ko si owo iwole, nitori e gan-an la se n pe awon ololufe ijoba fuji
atawon alafe eeyan gbogbo lati wa ba wa jegbadun ayeye pataki yii. Ohun kan ti
won nilo naa ni ki won ra MEGATO ati Mokole, ofifo ike egboogi mejeeji yii
gan-an ni won yoo fi wole, bee ni won yoo tun lanfaani repete lati jebun gidi.
Bi won ba se ra oja si ni won yoo se ko ebun repete lo sile.
“Anfaani wa fawon eeyan wa lati lo ra a lopo yanturu ni
ileese Oko Oloyun to wa ni No 51, Oke Ejigbo ni adojuko Ijaye junction niluu
Abeokuta, bee ni won tun le ri i ra lodo Iya Feranmi, ni Akin Olugbade ati ninu
oja Kuto niluu Abeokuta. Bakan naa lawon ti won wa ni Ijebu-Ode naa le ri ra ni
MEGATO House, Ejirin road, n’Ijebu-Ode.
0 Comments