Sannde ola, ojo kewaa osu keji odun yii ni gbajumo olorin
fuji nni, Remi Aluko, eni tawon eeyan tun mo si Igwe fuji yoo forin da awon
ololufe orin fuji laraya ni Bayeku, Iagbegbe Ikorodu, l’Ekoo.
Hotel nla kan ti oruko e n je Ambassador Villa lo te pepe
eto alarinrin yii si lati fi sami ipo otun ti ile itura naa wa bayii.
Ninu oro abenugan-an ileese ohun, Engineer
Dr Arowolo Abiola Saheed a.k.a Asoju ijoba Nigeria ti so pe, “Ipo ara
otun ni ileetura Ambassadors Villa wa bayii, a sese ko awon ohun igbalode kan
de, bee ni awon ohun elo lorisirisi ti won n lo nibe lasiko yii ti yato. Lati
le kede ara otun to ti ba ileetura ohun bayii, idi e niyen ta a fi te pepe eto
ariya yii, lati fi sami e, ki awon alafe eeyan gbogbo le wa darapo mo wa lati
jegbadun awon ohun meremere ta a ti ni loteeli ohun bayii.
O fi kun oro e pe, ajo kan ti ki i se tijoba rara, ti oruko
e n je ASOJU IJOBA FOUNDATION lo sagbateru ariya ohun, eyi ti yoo bere laago
mejila osan titi di aago mewaa asale.
Ojule kewaa Baale Nureni Ajibode street, niluu Igbogbo,
Bayeku, Ikorodu, l’Ekoo ni ileetura Ambassadors Villa wa, nibe gan an ni Remi
Aluko Igwe yoo ti so ilu sawon eeyan nibadi.
0 Comments