Lati fi sami eye ayajo ojoobi gbajumo olorin fiuji
nni, Alhaji Sulaimon Adio Atawewe, kaakiri agbaye lawon ololufe okunrin yii ti n
ki i lori ero alatagba, ti ero ibanisoro e paapaa, ko sinmi nigba kan.
Loni-in gan-an ni, iyen ojo ketadinlogbon osu keji
odun yii ni gbaju-gbaja olorin fuji naa maa n se ojoobi e.
Okan lara awon ololufe e, Ogbeni Taofeek Adio Akile ninu
ohun to ko sori ero alatagba FACEBOOK e lo ti so pe; “Mo ki Alhaji Sulaimon
Adio Atawewe, asoju ajo to n gbogun ti awon to n lo awon omode nilokulo, ki
Olorun tubo loora emi yin, iwo lokunrin gan-gan bii ogun ode, eni ti won ko
ominu, ti ko ko ominu won, Anobi fuji, Alaye gbogbo agbaye, igba odun, odun kan
ni o.”
Bakan naa ni Arabinrin Funmilola Omobolanle naa ko
tie bayii pe; Mo ki Baba Oloye ku oriire, Etu ko si oba o je, e o dagba ninu
ola nla ni o, bee igba odun, odun kan ni. E ku oriire o, baba agba”
Bi awon eeyan se n ki Sulaimon Adio Atawewe niyen o, ti won
si n gbadura fun un wi pe ki o pe daadaa laye ninu alaafia ati okiki ti ko
labawon kankan.
Ju gbogbo e lo, Sule Adio Atawewe naa ti soro o, o loun dupe
lowo Olorun to je ki ojo oni waye, bee lo ti fi da awon ololufe e loju wi pe laipe
yii ni won yoo tun gbo tuntun latodo oun, pelu orin fuji aladun, eyi ti yoo
migboro titi. Bakan naa lo ro won ki won
lo ra awon eyi to wa nita to n se daadaa lowo lasiko yii.
0 Comments