Ninu awon osere tiata ti won maa n saponle awon
eeyan daadaa ninu ise sinima, o fe je pe Baba Suwe ni. Okunrin yii gan-an la fe
so pe oun lo so awon osere tiata deni to maa n ki eeyan ninu sinima bii igba ti
Wasiu Ayinde ba n saponle eeyan lasiko to ba n korin fuji lowo.
Fun opolopo eeyan to ba ti lanfaani lati wo
sinima Baba Suwe, bi okunrin alawada yii ba se n daruko oloselu kan, bee ni yoo
maa daruko awon gbajumo nla nla paapaa awon to n gbe niluu oyinbo lohun-un, ti
yoo si maa sapejuwe iru eeya n ti won je, ati bi awon se sunmo ara to.
Okan pataki ninu awon eeyan ti Baba Suwe maa n
polongo e ju ninu sinima ni gomina ipinle Eko tele, Asiwaju Bola Tinubu, o fe
ma si sinima e kan bayii ti Babatunde Omidina ko ti ni polongo Tinubu. Bi o ba
se n so nipa eeyan rere ti okunrin oloselu yii n se, bee naa ni yoo maa je ki
gbogbo eeyan mo wi pe, ajosepo nla wa laarin awon, ati pe eni ti oun ko le fi
sere ni, ti tohun naa ko le foro oun sere. Bi Baba Suwe se n se yii, bee gege
naa lo se lasiko igba ti Babatunde Raji Fashola naa fi wa lori ipo.
Ni bayii ti okunrin osere alawada nla yii wa
ninu idaamu, ohun tawon eeyan n so ni pe, yoo dara ti awon oloselu yii ba le lo
ipo won lati ran an lowo, paapaa nipa itoju e, ti alaafia yoo fi to o lara, ti
yoo si tun pada sidii ise sinima e bii tele.
Won ni, ipo ti Baba Suwe wa lasiko yii ko daa
rara, ati pe nise ni okunrin naa de ara e mole, ti ki i fe jade sita mo, nitori
itiju.
Bi awon eeyan kan se n ke si awon oloselu,
paapaa Asiwaju Bola Tinubu ati Babatunde Raji Fashola, bee lawon kan naa so pe,
itiju nla lo maa je fun egbe awon osere, ti won ko ba le dide iranlowo si
okunrin alawada yii.
Won ni ohun to ye ki o je egbe naa logun ni bi
won yoo se gba emi eni to ba n saisan ninu won la, dipo sise aisun asale osere,
eyi ti won n pe ni (Artist Candle night) fun eyikeyi to ba ku lojiji ninu won.
Okunrin kan ti a ba soro lagbegbe Ikorodu so pe,
“Nibi ti aye la ju de loni-in, ko ye ki igbe aye awon osere maa ri bo se n ri
yii. Yato fun pe won n polongo iranlowo fun eyi to ba ni isoro ninu won, awon
funra won gan-an ye ki won ni eto pataki, bii eto adoju-tofo, ti yoo wa fun iranwo
enikeni ninu won to ba ku die kaato fun. Bakan naa ni won gbodo fi ife maa ba
ara won lo, ko ye ko je pe lasiko igba ti irawo okan ninu won ba n tan ni won a
maa polongo e. O tun se patak ki eni ti irawo e ba n tan lowo naa sora se, ko
ranti wi pe igba maa n yi o, ki Olorun saanu Baba Suwe, ki alaafia to peye le
to o lara.
Te o ba gbagbe, o se die ti awuyewuye aisan to n
se Baba Suwe yii ti wa nita, sugbon ohun kan to maa n ya opo lenu ni pe, ni kete
ti iroyin ba ti gbe e wi pe okunrin alawada yii n saisan, lojuese loun naa a ti
sare bo sita ta a so pe ko si ohun kan bayii to n se oun.
Sa o, awon ti won sunmo on, ti won lanfaani lati
ri i so pe, ninu inira lo wa, ati pe asisan n se e gidigidi, bee lo nilo
iranlowo gbogbo omo Nigeria ki ara e le ya, ko le raaye jere gbogbo wahala to
ti se laaaro ojo e nidii ise sinima.
0 Comments