Ni bayii, ko si
awuyewuye kankan mo lori egbe oselu ti Otunba Alao Akala, gomina ipinle Oyo tele
wa mo bayii, nitori okunrin oloselu naa ti so pe omo egbe oselu APC loun n se
bayii.
Lasiko ti gomina
ipinle Ekiti, Dokita Kayode Fayemi yo si okunrin oloselu omo ilu Ogbomoso yii
were nile e ni Ibadan lo so oro ohun wi pe oun ti pada sile, ati pe egbe oselu
APC gan-an nile ti oun n so.
Saaju asiko yii ni
iroyin ti koko gbe e wi pe Alao Akala ati Bola Tinubu ti koko pade l’Ekoo, nibi
ti awon oro ajoso kan ti koko waye lori bi okunrin oloselu yii yoo se sise fun eni
to n dije dupo gomina labe asia egbe oselu APC nipinle Oyo, bo tile je pe ipo
yen gan-an loun naa fe lo fun.
Te o ba gbagbe, ninu
osu kewaa odun 2018 gan-an ni Alao Akala binu kuro ninu egbe oselu APC nigba ti
won ko fun un ni tikeeti lati dije dupo gomina Oyo.
Sa o, Tosde Ojobo ose
yii la gbo pe Alao Akala ati awon molebi e, Oluwakemi Alao Akala, omo e
okunrin, Olamiju ati oga agba fun eto ipolongo ibo e, Wale Ohu lo ba Tinubu nile
ni Bourdillon ni Ikoyi, l’Ekoo.
Gege bi a se gbo, won
ni, ni kete ti Gomina Abiola Ajimobi ti fidi remi ninu ibo to koja, ti Alhaji Atiku
Abubakar si jawe olubori, ni idaamu nla ti ba awon Bola Tinubu, ti won si n wa
gbogbo ona ti oludije gomina nipinle naa, Adebayo Adelabu ko fi ni i fidi remi.
Won ni pelu ibo ti
awon eeyan ipinle Oyo di koja yii, o han daju wi pe egbe oselu APC ti su won
nipinle Oyo, ati pe isoro gan an ni yoo je fun won lati le ri aseyori gidi kan
se ninu ibo gomina ati tawon asofin to n bo laipe yii.
Okan lara awon omo egbe oselu ohun to ba wa soro so
pe, “Omo Ibadan ni Seyi Makinde, to n dije labe asia egbe oselu PDP ati Adebayo
Adelabu, ti egbe oselu APC, ohun to si daju ni pe, nise ni awon mejeeji yii jo
maa pin ibo Ibadan si meji ni. Nibe yen gan-an lawon agba oje nidii oselu ti wo
o wi pe Adebayo Alao Akala maa wulo gidi gan-an nitori yoo lo ipo e gege bii
asaaju oloselu niluu Ogbomoso fi ko ibo fun egbe oselu APC.”
Siwaju si i, eni to
ba wa soro yii so pe, saaju asiko yii gan-an ni egbe ti so fun Gomina Abiola
Ajimobi wi pe ko sise lori bi yoo se fa Alao Akala mora, sugbon to so pe ko si
ewu kankan, ibo ipinle Oyo, biba loun yoo ko fun egbe oselu oun, iyebn APC.
Sa o, ewu ti gomina
yii so pe ko si gan-an lo pada ko idaamu ba a, pelu boun gan-an se kuna lati
wole sipo seneto.
Lara ohun ti won lo
koba egbe oselu ohun nipinle Oyo ni awon oro oye ti gomina naa lo da si. Won ni
ohun to se yii ko dun mo opolopo ninu n’Ibadan, nibe gan-an ni won ti n duro de
e lati ko o logbon gidi.
Ni bayii, ti awon
abenugan-an nidii oselu ninu egbe APC ti so fun Alao Akala wi pe ko fi egbe e
ADP to ti fe dije dupo gomina sile ko wa sise fun APC lori bi omo Adelabu
Penkelemeesi yoo se wole, won lo jo pe oro adehun nla ti waye laarin won niyen.
Bee ni won lo to tun see
se ki won ba Alao Akala naa wa nnkan ninu ijoba Buhari ni kete ti gbogbo e ba
ti ri bi won se n fe.
Kayode Fayemi ni tie
lasiko to wa Alao Akala wa si Ibadan ni okunrin yii sapejuwe gomina ipinle Oyo
tele ohun gege bi agba oselu ti oun maa n bowo fun. Bee lo so pe oun fe fi da gbogbo
awon eeyan ipinle Oyo loju wi pe, Alao Akala ti pada sinu egbe oselu APC,
nitori nibe gan-an ni aye ijokoo irorun e wa.
0 Comments